Sáàmù 21:1-13

Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì. 21  Jèhófà, inú okun rẹ ni ọba ti ń yọ̀;+Sì wo bí ó ti ń fẹ́ láti kún fún ìdùnnú gidigidi nínú ìgbàlà rẹ!+  2  Ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn-àyà rẹ̀ fún un,+Ìwọ kò sì fawọ́ ìdàníyàn ètè rẹ̀ sẹ́yìn.+ Sélà.  3  Nítorí pé ìwọ tẹ̀ síwájú láti fi àwọn ìbùkún ohun rere pàdé rẹ̀,+Ìwọ sì fi adé wúrà tí a yọ́ mọ́ dé e ní orí.+  4  Ó béèrè ìwàláàyè lọ́wọ́ rẹ. Ìwọ fi fún un,+Ọjọ́ gígùn fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+  5  Ògo rẹ̀ tóbi nínú ìgbàlà rẹ.+Iyì àti ọlá ńlá ni ìwọ fi sí i lára.+  6  Nítorí pé ìwọ sọ ọ́ di alábùkún gidigidi títí láé;+Ìwọ fi ayọ̀ yíyọ̀ tí ó wà ní ojú rẹ mú kí ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.+  7  Nítorí pé ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà,+Àní nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Ẹni Gíga Jù Lọ. A kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+  8  Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ rí;+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí ó kórìíra rẹ rí.  9  Ìwọ yóò sọ wọ́n di ìléru oníná ní àkókò tí o yàn kalẹ̀ fún fífún wọn ní àfiyèsí.+Jèhófà yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, iná yóò sì jẹ wọ́n run.+ 10  Èso wọn ni ìwọ yóò pa run kúrò lórí ilẹ̀ ayé pàápàá,+Àti ọmọ wọn kúrò nínú àwọn ọmọ ènìyàn.+ 11  Nítorí pé wọ́n ti dojú ohun tí ó burú kọ ọ́;+Wọ́n ti gbìrò àwọn èrò-ọkàn tí wọn kò lè mú ṣẹ.+ 12  Nítorí tí ìwọ yóò mú kí wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà ní sísá+Nípasẹ̀ okùn ọrun rẹ tí o múra de ojú wọn.+ 13  Kí a gbé ọ ga nínú okun rẹ, Jèhófà.+Àwa yóò kọrin, a ó sì kọ orin atunilára sí agbára ńlá rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé