Sáàmù 20:1-9
Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì.
20 Kí Jèhófà dá ọ lóhùn ní ọjọ́ wàhálà.+Kí orúkọ Ọlọ́run Jékọ́bù dáàbò bò ọ́.+
2 Kí ó fi ìrànlọ́wọ́ rẹ ránṣẹ́ láti ibi mímọ́,+Kí ó sì gbé ọ ró láti Síónì pàápàá.+
3 Kí ó rántí gbogbo ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn rẹ,+Kí ó sì gba ọrẹ ẹbọ sísun rẹ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó lọ́ràá.+ Sélà.
4 Kí ó fi fún ọ ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn-àyà rẹ,+Kí ó sì mú gbogbo ète rẹ ṣẹ.+
5 Àwa yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ìgbàlà rẹ,+Àti pé ní orúkọ Ọlọ́run wa ni a óò gbé àwọn ọ̀págun wa sókè.+Kí Jèhófà mú gbogbo ìbéèrè rẹ ṣẹ.+
6 Nísinsìnyí ni mo wá mọ̀ pé Jèhófà ń gba ẹni àmì òróró rẹ̀ là dájúdájú.+Ó ń dá a lóhùn láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀+Pẹ̀lú àwọn ìṣe agbára ńlá tí ń gbani là ti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.+
7 Àwọn kan ń sọ nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn mìíràn sì ń sọ nípa ẹṣin,+Ṣùgbọ́n, ní tiwa, àwa yóò máa sọ nípa orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.+
8 Àwọn wọ̀nyẹn ti wó, wọ́n sì ti ṣubú;+Ṣùgbọ́n ní tiwa, àwa ti dìde, kí a lè mú wa padà bọ̀ sípò.+
9 Jèhófà, gba ọba là!+Òun yóò dá wa lóhùn ní ọjọ́ tí a bá pè é.+

