Sáàmù 2:1-12

2  Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi wà nínú ìrúkèrúdò,+Tí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì ń sọ nǹkan òfìfo lábẹ́lẹ̀?+   Àwọn ọba ilẹ̀ ayé mú ìdúró wọn,+Àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì ti wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan+Lòdì sí Jèhófà+ àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀,+   Wọ́n wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a fa ọ̀já wọn já+Kí a sì ju okùn wọn nù kúrò lọ́dọ̀ wa!”+   Ẹni náà tí ó jókòó ní ọ̀run+ yóò rẹ́rìn-ín;Jèhófà yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín.+   Ní àkókò yẹn, òun yóò sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ìbínú rẹ̀,+Yóò sì kó ìyọnu bá wọn nínú ìkannú gbígbóná rẹ̀,+   Yóò wí pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ+Lórí Síónì,+ òkè ńlá mímọ́ mi.”+   Ẹ jẹ́ kí n tọ́ka sí àṣẹ àgbékalẹ̀ Jèhófà;Ó ti wí fún mi pé: “Ìwọ ni ọmọ mi;+Òní ni èmi, àní èmi, di baba rẹ.+   Béèrè lọ́wọ́ mi,+ kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ+Àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ.+   Ìwọ yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn,+Bí ohun èlò amọ̀kòkò ni ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú.”+ 10  Wàyí o, ẹ̀yin ọba, ẹ lo ìjìnlẹ̀ òye;Ẹ gba ìtọ́sọ́nà, ẹ̀yin onídàájọ́ ilẹ̀ ayé.+ 11  Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Jèhófà+Kí ẹ sì kún fún ìdùnnú ti ẹ̀yin ti ìwárìrì.+ 12  Ẹ fi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu,+ kí ìbínú Rẹ̀ má bàa ru,Kí ẹ má bàa sì ṣègbé ní ọ̀nà náà,+Nítorí pé ìbínú rẹ̀ tètè máa ń ru sókè.+Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tí ń sá di í.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé