Sáàmù 18:1-50

Sí olùdarí. Ti ìránṣẹ́ Jèhófà, ti Dáfídì, ẹni tí ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ orin yìí fún Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà dá a nídè kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti kúrò ní ọwọ́ Sọ́ọ̀lù.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: 18  Èmi yóò ní ìfẹ́ni fún ọ, ìwọ Jèhófà okun mi.+   Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.+Ọlọ́run mi ni àpáta mi. Èmi yóò sá di í,+Apata mi àti ìwo ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi.+   Jèhófà, Ẹni tí ó yẹ fún ìyìn, ni èmi yóò ké pè,+A ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.+   Àwọn ìjàrá ikú ká mi mọ́;+Ìkún omi ayaluni lójijì ti àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun sì ń kó ìpayà bá mi ṣáá.+   Àní àwọn ìjàrá Ṣìọ́ọ̀lù yí mi ká;+Àwọn ìdẹkùn ikú kò mí lójú.+   Mo ń ké pe Jèhófà ṣáá nínú wàhálà mi,Mo sì ń kígbe sí Ọlọ́run mi fún ìrànlọ́wọ́.+Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn mi láti inú tẹ́ńpìlì rẹ̀,+Igbe mi níwájú rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀ wàyí.+   Ilẹ̀ ayé sì bẹ̀rẹ̀ sí mì, ó sì mì jìgìjìgì,+Ṣìbáṣìbo sì bá àwọn ìpìlẹ̀ òkè ńláńlá pàápàá,+Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí pé a ti mú un bínú.+   Èéfín gòkè lọ láti ihò imú rẹ̀, iná láti ẹnu rẹ̀ sì ń jẹ run nìṣó;+Àwọn ẹyín iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.   Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ọ̀run wálẹ̀, ó sì sọ̀ kalẹ̀.+Ìṣúdùdù nínípọn sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 10  Ó sì ń gun kérúbù bọ̀, ó sì ń fò bọ̀,+Ó sì ń bọ̀ fẹẹ-fẹẹ-fẹẹ lórí ìyẹ́ apá ẹ̀mí kan.+ 11  Nígbà náà ni ó fi òkùnkùn ṣe ibi ìlùmọ́ rẹ̀,+Gbogbo àyíká rẹ̀ gẹgẹ́ bí àtíbàbà rẹ̀,Omi ṣíṣú, àwọsánmà nínípọn.+ 12  Láti inú ìtànyòò tí ó wà ní iwájú rẹ̀ ni àwọsánmà rẹ̀ tí ó kọjá lọ wà,+Yìnyín àti àwọn ẹyín iná.+ 13  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí sán ààrá ní ọ̀run,+Ẹni Gíga Jù Lọ sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ ohùn rẹ̀ jáde,+Yìnyín àti àwọn ẹyín iná tí ń jó. 14  Ó sì ń rán àwọn ọfà rẹ̀ jáde ṣáá, kí ó lè tú wọn ká;+Ó sì ta mànàmáná jáde, kí ó lè kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+ 15  Ojú ìṣàn omi sì di rírí,+Àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ eléso sì di títú síta+Láti inú ìbáwí rẹ mímúná, Jèhófà, láti inú ìtújáde èémí ihò imú rẹ.+ 16  Ó ń ránṣẹ́ láti ibi gíga lókè, ó ń mú mi,+Ó ń fà mí jáde kúrò nínú omi púpọ̀.+ 17  Ó ń dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+Àti kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi; nítorí pé wọ́n lágbára jù mí.+ 18  Wọ́n ń kò mí lójú ṣáá ní ọjọ́ àjálù mi,+Ṣùgbọ́n Jèhófà di ìtìlẹyìn fún mi.+ 19  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi jáde sí ibi aláyè gbígbòòrò;+Ó ń gbà mí sílẹ̀, nítorí pé ó ní inú dídùn sí mi.+ 20  Jèhófà san mí lẹ́san gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;+Ó san án padà fún mi gẹ́gẹ́ bí ìmọ́tónítóní ọwọ́ mi.+ 21  Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,+Èmi kò sì fi Ọlọ́run mi sílẹ̀ lọ́nà burúkú.+ 22  Nítorí gbogbo ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ wà ní iwájú mi,+Èmi kì yóò sì mú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.+ 23  Dájúdájú, èmi yóò fi ara mi hàn ní aláìní-àléébù lọ́dọ̀ rẹ̀,+Èmi yóò sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ìṣìnà níhà ọ̀dọ̀ mi.+ 24  Kí Jèhófà sì san án padà fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,+Gẹ́gẹ́ bí ìmọ́tónítóní ọwọ́ mi ní iwájú rẹ̀.+ 25  Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin;+Ìwọ yóò bá aláìní-àléébù, abarapá ọkùnrin lò lọ́nà àìlálèébù;+ 26  Sí ẹni tí ó mọ́, ìwọ yóò fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó mọ́;+Sí oníwà wíwọ́, ìwọ yóò fi ara rẹ hàn ní ọlọ́gbọ́n àyínìke;+ 27  Nítorí pé àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ni ìwọ yóò gbà là;+Ṣùgbọ́n àwọn ojú tí ó kún fún ìrera ni ìwọ yóò rẹ̀ wálẹ̀.+ 28  Nítorí ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, yóò tan fìtílà mi;+Ọlọ́run mi tìkára rẹ̀ yóò mú kí òkùnkùn mi mọ́lẹ̀.+ 29  Nítorí nípasẹ̀ rẹ, mo lè sáré ní ìgbéjàko ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí;+Àti pé nípasẹ̀ Ọlọ́run mi, mo lè gun ògiri.+ 30  Ní ti Ọlọ́run tòótọ́, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;+Àsọjáde Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.+Apata ni ó jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ń sá di í.+ 31  Nítorí pé ta ni Ọlọ́run yàtọ̀ sí Jèhófà?+Ta sì ni àpáta bí kò ṣe Ọlọ́run wa?+ 32  Ọlọ́run tòótọ́ ni Ẹni tí ń fi ìmí dì mí lámùrè gírígírí,+Òun yóò sì jẹ́ kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé,+ 33  Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ti egbin,+Ó sì mú mi dúró sórí àwọn ibi tí ó ga fún mi.+ 34  Ó ń kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,+Apá mi sì ti tẹ ọrun bàbà.+ 35  Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ,+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbé mi ró,+Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni yóò sọ mí di ńlá.+ 36  Ìwọ yóò ṣe àyè tí ó tóbi tó fún àwọn ìṣísẹ̀ mi lábẹ́ mi,+Dájúdájú, ọrùn ẹsẹ̀ mi kì yóò gbò yèpéyèpé.+ 37  Èmi yóò lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi yóò sì bá wọn;Èmi kì yóò sì padà títí wọn yóò fi pa run pátápátá.+ 38  Èmi yóò ṣẹ́ wọn sí wẹ́wẹ́, kí wọ́n má lè dìde mọ́;+Wọn yóò ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.+ 39  Ìwọ yóò sì fi ìmí dì mí lámùrè fún ogun;Ìwọ yóò mú kí àwọn tí ó dìde sí mi wó lulẹ̀ lábẹ́ mi.+ 40  Àti ní ti àwọn ọ̀tá mi, ìwọ yóò fún mi ní ẹ̀yìn ọrùn wọn dájúdájú;+Àti ní ti àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan, èmi yóò pa wọ́n lẹ́nu mọ́.+ 41  Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí olùgbàlà kankan,+Sí Jèhófà, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn ní ti tòótọ́.+ 42  Èmi yóò sì gún wọn kúnná bí ekuru níwájú ẹ̀fúùfù;+Bí ẹrẹ̀ ojú pópó ni èmi yóò dà wọ́n jáde.+ 43  Ìwọ yóò pèsè àsálà fún mi kúrò lọ́wọ́ àléébù wíwá àwọn ènìyàn náà.+Ìwọ yóò yàn mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.+Àwọn ènìyàn tí èmi kò mọ̀—wọn yóò sìn mí.+ 44  Ní gbígbọ́ àgbọ́sọ lásán, wọn yóò jẹ́ onígbọràn sí mi;+Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè alára yóò wá fi ìwárìrì tẹrí ba fún mi.+ 45  Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè alára yóò pòórá,Wọn yóò sì fi ìwárìrì jáde wá láti inú odi ààbò wọn.+ 46  Jèhófà ń bẹ,+ ìbùkún sì ni fún Àpáta mi,+Kí a sì gbé Ọlọ́run ìgbàlà mi ga.+ 47  Ọlọ́run tòótọ́ ni Olùpèsè ìgbẹ̀san fún mi;+Ó sì ń tẹ àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.+ 48  Ó ń pèsè àsálà fún mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi tí inú ń bí;+Ìwọ yóò gbé mi lékè àwọn tí ó dìde sí mi,+Ìwọ yóò dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ oníwà ipá.+ 49  Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi gbé ọ lárugẹ, Jèhófà, láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Ṣe ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ.+ 50  Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà ńlá fún ọba rẹ̀,+Ó sì ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ẹni àmì òróró rẹ̀,+Sí Dáfídì àti sí irú-ọmọ rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé