Sáàmù 17:1-15
Àdúrà Dáfídì.
17 Gbọ́ ohun tí í ṣe òdodo, Jèhófà; fiyè sí igbe ìpàrọwà mi;+Fi etí sí àdúrà mi tí kì í ṣe ti ètè ẹ̀tàn.+
2 Kí ìdájọ́ mi ti iwájú rẹ jáde lọ;+Kí ojú rẹ rí ìdúróṣánṣán.+
3 O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà mi, o ti ṣe àbẹ̀wò ní òru,+O ti yọ́ mi mọ́; ìwọ yóò ṣàwárí pé èmi kò pète-pèrò ibi.+Ẹnu mi kì yóò ré ìlànà kọjá.+
4 Ní ti ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn,Nípa ọ̀rọ̀ ètè rẹ ni èmi fi ń ṣọ́ra fún ipa ọ̀nà ọlọ́ṣà.+
5 Jẹ́ kí àwọn ìṣísẹ̀ mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin ní àwọn òpó ọ̀nà rẹ,+Nínú èyí tí a kì yóò ti mú kí àwọn ipasẹ̀ mi kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n dájúdájú.+
6 Èmi ké pè ọ́, nítorí tí ìwọ, Ọlọ́run, yóò dá mi lóhùn.+Dẹ etí sí mi. Gbọ́ àsọjáde mi.+
7 Mú kí àwọn ìṣe inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ àgbàyanu,+ ìwọ Olùgbàlà àwọn tí ń wá ibi ìsádiKúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+
8 Pa mí mọ́ bí ọmọlójú,+Fi mí pa mọ́ sábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,+
9 Nítorí àwọn ẹni burúkú tí wọ́n ti fi mí ṣe ìjẹ.Àwọn ọ̀tá ọkàn mi ń ká mi mọ́.+
10 Wọ́n ti fi ọ̀rá ara wọn bora;+Wọ́n ti fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìrera;+
11 Ní ti àwọn ìṣísẹ̀ wa, wọ́n ti yí wa ká wàyí;+Wọ́n gbé ojú wọn lé títẹ̀ kanlẹ̀.+
12 Ìrí rẹ̀ jẹ́ ti kìnnìún tí ń yánhànhàn láti fani ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ+Àti ti ẹgbọrọ kìnnìún tí ó jókòó sí àwọn ibi tí ó lùmọ́.
13 Jèhófà, dìde; kò ó lójú;+Mú un tẹrí ba; fi idà rẹ pèsè àsálà fún ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú,+
14 Kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ ọwọ́ rẹ, Jèhófà,+Kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ètò+ àwọn nǹkan yìí, àwọn tí ìpín wọ́n ń bẹ nínú ìgbésí ayé yìí,+Ikùn àwọn ẹni tí o sì ti fi ìṣúra rẹ ìkọ̀kọ̀ kún,+Tí a fi àwọn ọmọkùnrin tẹ́ lọ́rùn,+Àwọn tí ó to ohun tí wọ́n ṣẹ́ kù jọ pa mọ́ fún àwọn ọmọ wọn.+
15 Ní tèmi, inú òdodo ni èmi yóò ti rí ojú rẹ;+Dájúdájú, yóò tẹ́ mi lọ́rùn láti máa jí rí ìrísí rẹ.+

