Sáàmù 150:1-6
150 Ẹ yin Jáà!+Ẹ yin Ọlọ́run nínú ibi mímọ́ rẹ̀.+Ẹ yìn ín nínú òfuurufú okun rẹ̀.+
2 Ẹ yìn ín fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ alágbára ńlá.+Ẹ yìn ín ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu títóbi rẹ̀.+
3 Ẹ fi ìwo fífun yìn ín.+Ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù yìn ín.+
4 Ẹ fi ìlù tanboríìnì+ àti ijó àjóyípo+ yìn ín.Ẹ fi àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti fèrè ape+ yìn ín.
5 Ẹ fi àwọn aro tí ó ní ìró orin atunilára yìn ín.+Ẹ fi àwọn aro tí ń dún gooro yìn ín.+
6 Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.+Ẹ yin Jáà!+

