Sáàmù 15:1-5

Orin atunilára ti Dáfídì. 15  Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ?+Ta ni yóò máa gbé ní òkè ńlá mímọ́ rẹ?+   Ẹni tí ń rìn láìlálèébù,+ tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù+Tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+   Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́,+Kò ṣe ohun búburú kankan sí alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀,+Kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ojúlùmọ̀ rẹ̀ tímọ́tímọ́.+   Ní ojú rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí kò ní láárí jẹ́ ẹni tí a kọ̀,+Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ó ń bọlá fún.+Ó ti búra sí ohun tí ó burú fún ara rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò yí padà.+   Kò fi owó rẹ̀ fúnni ní èlé,+Kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sí aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.+Ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, a kì yóò mú un ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé