Sáàmù 148:1-14
148 Ẹ yin Jáà!+Ẹ yin Jèhófà láti ọ̀run,+Ẹ yìn ín ní àwọn ibi gíga.+
2 Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀.+Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.+
3 Ẹ yìn ín, oòrùn àti òṣùpá.+Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.+
4 Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọ̀run àwọn ọ̀run,+Àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ lókè ọ̀run.+
5 Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà;+Nítorí pé òun fúnra rẹ̀ ni ó pàṣẹ, a sì dá wọn.+
6 Ó sì mú kí wọ́n dúró títí láé, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+Ó ti fún wọn ní ìlànà, èyí tí kì yóò sì ré kọjá.+
7 Ẹ yin Jèhófà láti ilẹ̀ ayé,+Ẹ̀yin ẹran ńlá abàmì inú òkun àti gbogbo ẹ̀yin ibú omi,+
8 Ẹ̀yin iná àti yìnyín, ìrì dídì àti èéfín nínípọn,+Ìwọ ẹ̀fúùfù oníjì líle, tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,+
9 Ẹ̀yin òkè ńláńlá àti gbogbo ẹ̀yin òkè kéékèèké,+Ẹ̀yin igi eléso àti gbogbo ẹ̀yin kédárì,+
10 Ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ àti gbogbo ẹ̀yin ẹran agbéléjẹ̀,+Ẹ̀yin ohun tí ń rákò àti ẹ̀yin ẹyẹ abìyẹ́lápá,+
11 Ẹ̀yin ọba ilẹ̀ ayé+ àti gbogbo ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè,Ẹ̀yin ọmọ aládé+ àti gbogbo ẹ̀yin onídàájọ́ ilẹ̀ ayé,+
12 Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin+ àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú,+Ẹ̀yin arúgbó+ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin.+
13 Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà,+Nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ó ga ré kọjá ibi tí ó ṣeé dé.+Iyì rẹ̀ ń bẹ lókè ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.+
14 Òun yóò sì gbé ìwo àwọn ènìyàn rẹ̀ ga,+Ìyìn gbogbo àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,+Ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn tí ó sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.+Ẹ yin Jáà!+

