Sáàmù 146:1-10

146  Ẹ yin Jáà!+Máa yin Jèhófà, ìwọ ọkàn mi.+   Ṣe ni èmi yóò máa yin Jèhófà ní ìgbà ayé mi.+Ṣe ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà.+   Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú,+Tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.+   Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ,+ ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀;+Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.+   Aláyọ̀ ni ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jékọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀,+Ẹni tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀,+   Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+Òkun, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,+Ẹni tí ń pa òótọ́ mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+   Ẹni tí ń mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún fún àwọn tí a lù ní jìbìtì,+Ẹni tí ń fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa.+Jèhófà ń tú àwọn tí a dè sílẹ̀.+   Jèhófà ń la ojú àwọn afọ́jú;+Jèhófà ń gbé àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde;+Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo.+   Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn àtìpó;+Ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó ni ó ń mú ìtura bá,+Ṣùgbọ́n ọ̀nà+ àwọn ẹni burúkú ni ó ń ṣe ní wíwọ́.+ 10  Jèhófà yóò jẹ ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Àní Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì, láti ìran dé ìran.+Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé