Sáàmù 144:1-15

Ti Dáfídì. 144  Ìbùkún ni fún Jèhófà Àpáta mi,+Ẹni tí ń kọ́ ọwọ́ mi fún ìjà,+Àti ìka mi fún ogun;  2  Inú rere mi onífẹ̀ẹ́ àti ibi odi agbára mi,+Ibi gíga ààbò mi àti Olùpèsè àsálà fún mi,+Apata+ mi àti Ẹni tí mo sá di,+Ẹni tí ń tẹ àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.+  3  Jèhófà, kí ni ènìyàn jẹ́, tí ìwọ fi ń kíyè sí i,+Àní ọmọ ẹni kíkú,+ tí ìwọ fi ń gba tirẹ̀ rò?  4  Ènìyàn tìkára rẹ̀ jọ èémí àmíjáde lásán-làsàn;+Àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bí òjìji tí ń kọjá lọ.+  5  Jèhófà, tẹ ọ̀run rẹ wálẹ̀ kí o lè sọ̀ kalẹ̀;+Fọwọ́ kan àwọn òkè ńláńlá kí wọ́n lè rú èéfín.+  6  Mú kí mànàmáná kọ, kí o lè tú wọn ká;+Rán àwọn ọfà rẹ jáde, kí o lè kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+  7  Na ọwọ́ rẹ jáde láti ibi gíga;+Dá mi sílẹ̀ lómìnira, kí o sì dá mi nídè lọ́wọ́ omi púpọ̀,+Kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,+  8  Àwọn tí ẹnu wọn ń sọ ohun àìjóòótọ́,+Àwọn tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.+  9  Ọlọ́run, orin tuntun ni èmi yóò máa kọ sí ọ.+Ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá ni èmi yóò máa fi kọ orin atunilára sí ọ,+ 10  Ẹni tí ń fún àwọn ọba ní ìgbàlà,+Ẹni tí ń dá Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ idà tí ń ṣeni léṣe.+ 11  Dá mi sílẹ̀ lómìnira, kí o sì dá mi nídè ní ọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,+Àwọn tí ẹnu wọn ti sọ ohun àìjóòótọ́,+Àwọn tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké,+ 12  Àwọn tí ó wí pé: “Àwọn ọmọkùnrin wa dà bí àwọn ọ̀gbìn kéékèèké tí ó dàgbà ní ìgbà èwe wọn,+Àwọn ọmọbìnrin wa dà bí àwọn igun-igun tí a gbẹ́ bí ọnà ààfin, 13  Àwọn àró wa kún, wọ́n ń mú ọ̀kan-kò-jọ̀kan èso jáde,+Àwọn agbo ẹran wa ń pọ̀ sí i ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ọ̀kan ń di ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá, ní àwọn ojú pópó wa, 14  Ẹrù ń wọ àwọn ẹran ọ̀sìn wa lọ́rùn, láìsí yíya èyíkéyìí, oyún kò sì ṣẹ́ lára wọn,+Kò sì sí igbe ẹkún rárá ní àwọn ojúde ìlú wa.+ 15  Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ fún!”Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé