Sáàmù 140:1-13
Fún olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì.
140 Gbà mí sílẹ̀, Jèhófà, lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;+Kí o fi ìṣọ́ ṣọ́ mi àní lọ́wọ́ oníwà ipá,+
2 Àwọn tí ó ti pète-pèrò àwọn ohun búburú nínú ọkàn-àyà wọn,+Àwọn tí ń gbéjà kò mí láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ bí ẹni pé nínú àwọn ogun.+
3 Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ti ejò;+Oró paramọ́lẹ̀ abìwo wà lábẹ́ ètè wọn.+ Sélà.
4 Pa mí mọ́, Jèhófà, lọ́wọ́ ẹni burúkú;+Kí o fi ìṣọ́ ṣọ́ mi àní lọ́wọ́ oníwà ipá,+Àwọn tí ó ti pète-pèrò láti taari àwọn ìṣísẹ̀ mi.+
5 Àwọn tí ó gbé ara wọn ga ti fi pańpẹ́ pa mọ́ dè mí;+Àwọn ìjàrá sì ni wọ́n ti nà jáde gẹ́gẹ́ bí àwọ̀n lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ọ̀nà.+Àwọn ìdẹkùn ni wọ́n ti dẹ dè mí.+ Sélà.
6 Mo wí fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.+Jèhófà, fi etí sí ohùn ìpàrọwà mi.”+
7 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ okun ìgbàlà mi,+Ìwọ ti dáàbò bo orí mi ní ọjọ́ agbo ọmọ ogun adìhámọ́ra.+
8 Jèhófà, má yọ̀ǹda àwọn ìfàsí-ọkàn ẹni burúkú fún un.+Má ṣagbátẹrù ìdìmọ̀lù rẹ̀, kí a má bàa gbé wọn ga.+ Sélà.
9 Ní ti orí àwọn tí ó yí mi ká,+Kí ìjàngbọ̀n ètè wọn bò wọ́n.+
10 Kí a da ẹyín iná sí wọn lórí.+Jẹ́ kí a mú kí wọ́n ṣubú sínú iná,+ sínú àwọn kòtò olómi, kí wọ́n má bàa dìde.+
11 Ẹlẹ́nu-ún-gbọ̀rọ̀—má ṣe jẹ́ kí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ilẹ̀ ayé.+Oníwà ipá—jẹ́ kí ibi pàápàá máa fi ìsọ́gọ léraléra ṣọdẹ rẹ̀.+
12 Èmi mọ̀ dunjú pé Jèhófà yóò ṣe+Ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, èyíinì ni ìdájọ́ àwọn òtòṣì.+
13 Dájúdájú, àwọn olódodo pàápàá yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;+Àwọn adúróṣánṣán yóò máa gbé níwájú rẹ.+

