Sáàmù 138:1-8
Ti Dáfídì.
138 Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ.+Iwájú àwọn ọlọ́run mìíràn ni èmi yóò ti máa kọ orin atunilára sí ọ.+
2 Èmi yóò tẹrí ba síhà tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ,+Èmi yóò sì gbé orúkọ rẹ lárugẹ,+Nítorí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́+ àti nítorí òótọ́ rẹ.+Nítorí pé ìwọ ti gbé àsọjáde+ rẹ ga lọ́lá àní lékè gbogbo orúkọ rẹ.+
3 Ní ọjọ́ tí mo pè, ìwọ sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn;+Ìwọ bẹ̀rẹ̀ sí fi okun sọ mí di aláìṣojo nínú ọkàn mi.+
4 Gbogbo ọba ilẹ̀ ayé yóò gbé ọ lárugẹ, Jèhófà,+Nítorí tí wọn yóò ti gbọ́ àwọn àsọjáde ẹnu rẹ.
5 Wọn yóò sì máa kọrin nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà,+Nítorí pé ògo Jèhófà pọ̀.+
6 Nítorí pé Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀;+Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.+
7 Bí mo bá rìn nínú wàhálà, ìwọ yóò pa mí mọ́ láàyè.+Ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ nítorí ìbínú àwọn ọ̀tá mi,+Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí là.+
8 Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò ṣe àṣepé ohun tí ó ṣàǹfààní fún mi.+Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+Má ṣe kọ àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tì.+

