Sáàmù 137:1-9

137  Lẹ́bàá àwọn odò Bábílónì+—ibẹ̀ ni a jókòó.+Àwa sì sunkún nígbà tí a rántí Síónì.+  2  Orí àwọn igi pọ́pílà+ tí ń bẹ ní àárín rẹ̀Ni a gbé àwọn háàpù+ wa kọ́.  3  Nítorí pé níbẹ̀, àwọn tí ó mú wa ní òǹdè béèrè àwọn ọ̀rọ̀ orin+ lọ́wọ́ wa,Àti àwọn tí ń fi wá ṣe ẹlẹ́yà—wọ́n béèrè fún ayọ̀ yíyọ̀+ pé:“Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa.”+  4  Báwo ni àwa ṣe lè kọ orin Jèhófà+Ní ilẹ̀ òkèèrè?+  5  Bí èmi bá gbàgbé rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù,+Kí ọwọ́ ọ̀tún mi gbàgbé.  6  Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu mi,+Bí èmi kì yóò bá rántí rẹ,+Bí èmi kì yóò bá mú kí Jerúsálẹ́mù gòkèRé kọjá olórí ìdí tí mo ní fún ayọ̀ yíyọ̀.+  7  Jèhófà, rántí+ ọjọ́ Jerúsálẹ́mù+ ní ti àwọn ọmọ Édómù,+Àwọn tí ó wí pé: “Tú u sí borokoto! Tú u sí borokoto dé ìpìlẹ̀ àárín rẹ̀!”+  8  Ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì, tí a ó fi ṣe ìjẹ,+Aláyọ̀ ni ẹni náà yóò jẹ́, tí yóò san án fún ọ+Pẹ̀lú irú ìlòsíni tìrẹ tí o fi bá wa lò.+  9  Aláyọ̀ ni ẹni náà yóò jẹ́, tí yóò gbá ọ mú, tí yóò sì fọ́+Àwọn ọmọ rẹ túútúú mọ́ àpáta gàǹgà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé