Sáàmù 135:1-21

135  Ẹ yin Jáà!+Ẹ yin orúkọ Jèhófà,+ Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+   Ẹ̀yin tí ń dúró nínú ilé Jèhófà,+Nínú àwọn àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.+    Ẹ yin Jáà, nítorí tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere.+Ẹ kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ̀, nítorí tí ó dùn mọ́ni.+   Nítorí pé Jáà ti yan Jékọ́bù fún ara rẹ̀,+Ó ti yan Ísírẹ́lì fún àkànṣe dúkìá rẹ̀.+   Nítorí tí èmi alára mọ̀ dáadáa pé Jèhófà tóbi,+Olúwa wa sì ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.+   Ohun gbogbo tí Jèhófà ní inú dídùn sí láti ṣe ni ó ti ṣe+Ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé, ní òkun àti gbogbo ibú omi.+   Ó ń mú kí oruku lọ sókè láti ìkángun ilẹ̀ ayé;+Àní ó ti ṣe àwọn ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ fún òjò;+Ó ń mú ẹ̀fúùfù jáde wá láti inú àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ rẹ̀,+   Ẹni tí ó ṣá àwọn àkọ́bí Íjíbítì balẹ̀,+Àti ènìyàn àti ẹranko.+   Ó rán àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sáàárín rẹ, ìwọ Íjíbítì,+Sára Fáráò àti sára gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀;+ 10  Ẹni tí ó ṣá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè balẹ̀,+Tí ó sì pa àwọn ọba tí ó jẹ́ alágbára gíga,+ 11  Àní Síhónì ọba àwọn Ámórì+Àti Ógù ọba Báṣánì+Àti gbogbo àwọn ìjọba Kénáánì,+ 12  Ẹni tí ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni gẹ́gẹ́ bí ogún,+Bí ogún fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 13  Jèhófà, orúkọ rẹ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+Jèhófà, ìrántí rẹ jẹ́ láti ìran dé ìran.+ 14  Nítorí tí Jèhófà yóò gba ẹjọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ rò,+Yóò sì kẹ́dùn àní nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+ 15  Fàdákà àti wúrà ni òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè,+Iṣẹ́ ọwọ́ ará ayé.+ 16  Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ nǹkan kan;+Wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè rí nǹkan kan;+ 17  Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè fi etí sí nǹkan kan.+Pẹ̀lúpẹ̀lù, kò sí ẹ̀mí kankan ní ẹnu wọn.+ 18  Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóò dà bí àwọn gan-an,+Gbogbo ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+ 19  Ilé Ísírẹ́lì, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+Ilé Áárónì, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+ 20  Ilé Léfì, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+Ẹ̀yin olùbẹ̀rù Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.+ 21  Ìbùkún ni fún Jèhófà láti Síónì wá,+Ẹni tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.+Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé