Sáàmù 132:1-18
Orin Ìgòkè.
132 Jèhófà, rántí nípa Dáfídì+Gbogbo títẹ́ tí a tẹ́ ẹ lógo;+
2 Bí ó ti búra fún Jèhófà,+Bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ẹni Alágbára+ Jékọ́bù+ pé:
3 “Dájúdájú, èmi kì yóò lọ sínú àgọ́ ilé mi.+Èmi kì yóò gorí àga ìnàyìn tí ń bẹ nínú yàrá ìrọ̀gbọ̀kú mi títóbi lọ́lá,+
4 Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,+Tàbí ìtòògbé fún ojú mi títàn yanran,+
5 Títí èmi yóò fi rí ibì kan fún Jèhófà,+Àgọ́ ìjọsìn títóbi lọ́lá fún Ẹni Alágbára Jékọ́bù.”+
6 Wò ó! Àwa ti gbọ́ nípa rẹ̀ ní Éfúrátà,+Àwa ti rí i ní àwọn pápá inú igbó.+
7 Ẹ jẹ́ kí a wá sínú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀ títóbi lọ́lá;+Ẹ jẹ́ kí a tẹrí ba níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.+
8 Dìde, Jèhófà, sí ibi ìsinmi rẹ,+Ìwọ àti àpótí+ okun rẹ.+
9 Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ alára,+Kí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sì máa fi ìdùnnú ké jáde.+
10 Ní tìtorí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ,+Má ṣe yí ojú ẹni àmì òróró rẹ padà.+
11 Jèhófà ti búra fún Dáfídì,+Lóòótọ́, kì yóò fà sẹ́yìn kúrò nínú rẹ̀+ pé:“Lára èso ikùn rẹ+Ni èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.+
12 Bí àwọn ọmọ rẹ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́+Àti àwọn ìránnilétí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,+Títí láé ni àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú+Yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ rẹ.”+
13 Nítorí pé Jèhófà ti yan Síónì;+Ó ti yánhànhàn fún un gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún ara rẹ̀+ pé:
14 “Èyí ni ibi ìsinmi mi títí láé;+Ìhín ni èmi yóò máa gbé, nítorí pé mo ti yánhànhàn fún un.+
15 Àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ ni èmi yóò bù kún láìkùnà.+Àwọn òtòṣì rẹ̀ ni èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ lọ́rùn.+
16 Àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ni èmi yóò fi ìgbàlà wọ̀;+Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ yóò sì fi ìdùnnú ké jáde láìkùnà.
17 Ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú kí ìwo Dáfídì yọ.+Mo ti ṣètò fìtílà fún ẹni àmì òróró mi.+
18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀;+Ṣùgbọ́n adé dáyádémà+ rẹ̀ yóò gbilẹ̀ lórí rẹ̀.”+

