Sáàmù 130:1-8

Orin Ìgòkè. 130  Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́, Jèhófà.+   Jèhófà, gbọ́ ohùn mi.+Kí etí rẹ sì ṣí sí ohùn ìpàrọwà mi.+   Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́,+ Jáà,Jèhófà, ta ni ì bá dúró?+   Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ,+Kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.+   Mo ti ṣèrètí, Jèhófà, ọkàn mi ti ṣèrètí,+Mo sì ti dúró de ọ̀rọ̀ rẹ̀.+   Ọkàn mi ti dúró de Jèhófà+Ju bí àwọn olùṣọ́ ti ń dúró de òwúrọ̀,+Tí wọ́n ń wọ̀nà fún òwúrọ̀.+   Kí Ísírẹ́lì máa bá a nìṣó ní dídúró de Jèhófà.+Nítorí pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bẹ lọ́dọ̀ Jèhófà,+Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ yanturu ìtúnràpadà sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.+   Òun tìkára rẹ̀ yóò sì tún Ísírẹ́lì rà padà kúrò nínú gbogbo ìṣìnà rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé