Sáàmù 13:1-6
Sí olùdarí. Orin atunilára ti Dáfídì.
13 Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí ìwọ yóò fi gbàgbé mi?+ Ṣé títí láé ni?+Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi ojú rẹ pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi?+
2 Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò ṣe ìdènà nínú ọkàn mi,Ẹ̀dùn-ọkàn nínú ọkàn-àyà mi ní ọ̀sán?Yóò ti pẹ́ tó tí a óò gbé ọ̀tá mi ga lé mi lórí?+
3 Wò mí; dá mi lóhùn, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi.Mú kí ojú mi tàn,+ kí n má bàa sùn lọ nínú ikú,+
4 Kí ọ̀tá mi má bàa sọ pé: “Mo ti borí rẹ̀!”Kí àwọn elénìní mi má bàa kún fún ìdùnnú nítorí pé a mú kí n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́.+
5 Ní tèmi, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+Jẹ́ kí ọkàn-àyà mi kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ.+
6 Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti bá mi lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.+

