Sáàmù 129:1-8
Orin Ìgòkè.
129 “Ó ti pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n ti ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi láti ìgbà èwe mi wá,”+Ni kí Ísírẹ́lì máa wí nísinsìnyí,+
2 “Ó ti pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n ti ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi láti ìgbà èwe mi wá;+Síbẹ̀, wọn kò tíì borí mi.+
3 Àwọn atúlẹ̀ ti túlẹ̀ lórí ẹ̀yìn mi pàápàá;+Wọ́n ti mú àwọn aporo wọn gùn.”
4 Olódodo ni Jèhófà.+Ó ti ké ìjàrá àwọn ẹni burúkú sí wẹ́wẹ́.+
5 Ojú yóò tì wọ́n, wọn yóò sì yí padà,+Gbogbo àwọn tí ó kórìíra Síónì.+
6 Wọn yóò dà bí koríko tútù ti orí òrùlé,+Èyí tí ó jẹ́ pé, kí a tó tu ú kúrò, ó ti gbẹ dànù,+
7 Èyí tí akárúgbìn kò fi kún ọwọ́ rẹ̀,+Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń kó ìtí jọ kò fi kún oókan àyà rẹ̀.
8 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé:“Kí ìbùkún Jèhófà wà lórí yín.+Àwa ti bù kún yín ní orúkọ Jèhófà.”+

