Sáàmù 128:1-6
Orin Ìgòkè.
128 Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà,+Tí ó ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.+
2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ làálàá ọwọ́ rẹ.+Aláyọ̀ ni ìwọ yóò jẹ́, yóò sì dára fún ọ.+
3 Aya rẹ yóò dà bí àjàrà tí ń so èso+Ní ìhà inú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ilé rẹ.Àwọn ọmọ rẹ yóò dà bí àwọn àgélọ́ igi ólífì+ yí tábìlì rẹ ká.
4 Wò ó! Bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe bù kún abarapá ọkùnrin+Tí ó bẹ̀rù Jèhófà.+
5 Jèhófà yóò bù kún ọ láti Síónì wá.+Kí ìwọ sì máa rí ire Jerúsálẹ́mù ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ,+
6 Kí o sì máa rí àwọn ọmọ-ọmọ rẹ.+Kí àlàáfíà wà lórí Ísírẹ́lì.+

