Sáàmù 127:1-5
Orin Ìgòkè. Ti Sólómọ́nì.
127 Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà,+Lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.+Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá ṣọ́ ìlú ńlá náà,+Lásán ni ẹ̀ṣọ́ wà lójúfò.+
2 Lásán ni ẹ ń dìde ní kùtùkùtù,+Tí ẹ ń pẹ́ kí ẹ tó jókòó,+Tí ẹ ń fi ìrora jẹ oúnjẹ.+Bẹ́ẹ̀ gan-an ni òun ń fi oorun fún olùfẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n.+
3 Wò ó! Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà;+Èso ikùn jẹ́ èrè.+
4 Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá,+Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe rí.+
5 Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi wọ́n kún+ apó rẹ̀.Ojú kì yóò tì wọ́n,+Nítorí tí wọn yóò bá àwọn ọ̀tá sọ̀rọ̀ ní ẹnubodè.

