Sáàmù 126:1-6

Orin Ìgòkè. 126  Nígbà tí Jèhófà kó àwọn òǹdè Síónì jọ padà,+Àwa dà bí àwọn tí ń lá àlá.+  2  Ní àkókò yẹn, ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,+Ahọ́n wa sì kún fún igbe ìdùnnú.+Ní àkókò yẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè+ pé:“Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wọn.”+  3  Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wa.+Àwa ti kún fún ìdùnnú.+  4  Jèhófà, kó ẹgbẹ́ àwọn òǹdè wa jọ padà,+Bí ojú ìṣàn omi ní Négébù.+  5  Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn+Yóò fi igbe ìdùnnú ká a.+  6  Láìkùnà, ẹni tí ń jáde lọ, àní tí ó ń sunkún,+Bí ó ti gbé irúgbìn ẹ̀kún àpò dání,+Láìkùnà, yóò fi igbe ìdùnnú wọlé wá,+Bí ó ti gbé àwọn ìtí rẹ̀ dání.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé