Sáàmù 125:1-5
Orin Ìgòkè.
125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+Dà bí Òkè Ńlá Síónì,+ tí a kò lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ṣùgbọ́n tí ó ń bẹ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
2 Jerúsálẹ́mù—bí àwọn òkè ńlá ti yí i ká,+Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yí àwọn ènìyàn rẹ̀ ká+Láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.+
3 Nítorí pé ọ̀pá aládé ti ìwà burúkú kì yóò máa bá a nìṣó ní wíwà+ lórí ìpín àwọn olódodo,Kí àwọn olódodo má bàa na ọwọ́ wọn lé ìwà àìtọ́ kankan.+
4 Jèhófà, ṣe rere sí àwọn ẹni rere,+Àní sí àwọn tí ó jẹ́ adúróṣánṣán nínú ọkàn-àyà wọn.+
5 Ní ti àwọn tí ń yà sí àwọn ọ̀nà wíwọ́ ti ara wọn,+Jèhófà yóò mú kí wọ́n lọ pẹ̀lú àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.+Àlàáfíà yóò wà lórí Ísírẹ́lì.+

