Sáàmù 124:1-8
Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.
124 “Ọpẹ́lọpẹ́ pé Jèhófà wà fún wa,”+Ni kí Ísírẹ́lì máa wí nísinsìnyí,+
2 “Ọpẹ́lọpẹ́ pé Jèhófà wà fún wa+Nígbà tí àwọn ènìyàn dìde sí wa,+
3 Nígbà náà, wọn ì bá ti gbé wa mì àní láàyè,+Nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa.+
4 Nígbà náà, omi pàápàá ì bá ti gbé wa lọ,+Àní ọ̀gbàrá ì bá ti kọjá lórí ọkàn wa.+
5 Nígbà náà, omi ìkùgbù+Ì bá ti kọjá lórí ọkàn wa.
6 Ìbùkún ni fún Jèhófà, tí kò fi wá fún wọn+Gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ fún eyín wọn.+
7 Ọkàn wa dà bí ẹyẹ tí ó ti yè bọ́+Lọ́wọ́ pańpẹ́ àwọn tí ń dẹ ìjẹ̀.+Pańpẹ́ ti ṣẹ́,+Àwa alára sì ti yè bọ́.+
8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ nínú orúkọ Jèhófà,+Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”+

