Sáàmù 123:1-4

Orin Ìgòkè. 123  Ìwọ ni mo gbé ojú mi sókè sí,+Ìwọ tí ń gbé ní ọ̀run.+  2  Wò ó! Bí ojú àwọn ìránṣẹ́ ti ń wo ọwọ́ ọ̀gá wọn,+Bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti ń wo ọwọ́ olúwa rẹ̀ obìnrin,+Bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Jèhófà Ọlọ́run wa,+Títí yóò fi fi ojú rere hàn sí wa.+  3  Fi ojú rere hàn sí wa, Jèhófà, fi ojú rere hàn sí wa;+Nítorí pé a ti fi ìfojú-tín-ín-rín rọ wá yó dẹ́múdẹ́mú.+  4  A ti fi ìfiniṣẹ̀sín àwọn tí ó wà ní ìdẹ̀rùn rọ ọkàn wa yó dẹ́múdẹ́mú,+Àní ìfojú-tín-ín-rín níhà ọ̀dọ̀ àwọn olùṣe fọ́ńté.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé