Sáàmù 122:1-9
Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì.
122 Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé:+“Jẹ́ kí a lọ+ sí ilé Jèhófà.”+
2 Ẹsẹ̀ wa dúró+Nínú àwọn ẹnubodè rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+
3 Jerúsálẹ́mù jẹ́ èyí tí a kọ́ bí ìlú ńlá+Tí a ti so pọ̀ nínú ìṣọ̀kanṣoṣo,+
4 Ibi tí àwọn ẹ̀yà gòkè lọ,+Àwọn ẹ̀yà Jáà,+Gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí fún Ísírẹ́lì+Láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ Jèhófà.+
5 Nítorí pé ibẹ̀ ni a gbé àwọn ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀ sí,+Àwọn ìtẹ́ fún ilé Dáfídì.+
6 Ẹ béèrè fún àlàáfíà Jerúsálẹ́mù.+Àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ ìlú ńlá, yóò bọ́ lọ́wọ́ àníyàn.+
7 Kí àlàáfíà máa bá a lọ nínú ohun àfiṣe-odi rẹ,+Àti òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn nínú àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ.+
8 Nítorí àwọn arákùnrin mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi ni èmi yóò ṣe sọ̀rọ̀ wàyí pé:+“Kí àlàáfíà wà nínú rẹ.”+
9 Nítorí ilé Jèhófà Ọlọ́run wa,+Ṣe ni èmi yóò máa wá ire fún ọ.+

