Sáàmù 121:1-8
Orin Ìgòkè.
121 Èmi yóò gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè ńlá.+Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?+
2 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá,+Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.+
3 Kò ṣeé ṣe kí òun jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+Kò ṣeé ṣe kí Ẹni tí ń ṣọ́ ọ tòògbé.+
4 Wò ó! Kì yóò tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sùn,+Ẹni tí ń ṣọ́ Ísírẹ́lì.+
5 Jèhófà ń ṣọ́ ọ.+Jèhófà ni ibòji+ rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+
6 Àní oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ọ̀sán,+Tàbí òṣùpá ní òru.+
7 Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ gbogbo ìyọnu àjálù.+Òun yóò máa ṣọ́ ọkàn rẹ.+
8 Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ìjáde rẹ àti ìwọlé rẹ+Láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.+

