Sáàmù 120:1-7

Orin Ìgòkè. 120  Jèhófà ni mo ké pè nínú wàhálà mi,+Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn.+  2  Jèhófà, dá ọkàn mi nídè lọ́wọ́ ètè èké,+Lọ́wọ́ ahọ́n àgálámàṣà.+  3  Kí ni ènìyàn yóò fi fún ọ, kí sì ni ènìyàn yóò fi kún un fún ọ,Ìwọ ahọ́n àgálámàṣà?+  4  Àwọn ọfà mímú ti alágbára ńlá,+Pa pọ̀ pẹ̀lú ẹyín iná àwọn igi wíwẹ́.+  5  Mo gbé, nítorí pé mo ti ṣe àtìpó ní Méṣékì!+Mo ti pàgọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgọ́ Kídárì.+  6  Fún àkókò pípẹ́ gan-an ni ọkàn mi ti fi pàgọ́+Pẹ̀lú àwọn olùkórìíra àlàáfíà.+  7  Èmi dúró fún àlàáfíà;+ ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀,+Wọ́n wà fún ogun.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé