Sáàmù 111:1-10
111 Ẹ yin Jáà!+
א [Áléfì]Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé Jèhófà lárugẹ+ב [Bétì]Nínú àwùjọ tímọ́tímọ́+ ti àwọn adúróṣánṣán àti ti àpéjọ.+
ג [Gímélì]
2 Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tóbi,+ד [Dálétì]Wíwá kiri ni wọ́n jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ó ní inú dídùn sí wọn.+
ה [Híì]
3 Ìgbòkègbodò rẹ̀+ jẹ́ iyì àti ọlá ńlá pàápàá,+ו [Wọ́ọ̀]Òdodo rẹ̀ sì dúró títí láé.+
ז [Sáyínì]
4 Ó ti ṣe ìrántí fún àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+
ח [Kétì]Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú.+
ט [Tétì]
5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+
י [Yódì]Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni òun yóò máa rántí májẹ̀mú rẹ̀.+
כ [Káfì]
6 Ó ti sọ agbára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀,+ל [Lámédì]Ní fífún wọn ní ogún àwọn orílẹ̀-èdè.+
מ [Mémì]
7 Òtítọ́ àti ìdájọ́ ni àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+נ [Núnì]Aṣeégbẹ́kẹ̀lé ni gbogbo àṣẹ ìtọ́ni tí ó ń fi fúnni,+
ס [Sámékì]
8 Èyí tí a tì lẹ́yìn dáadáa títí láé, fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ע [Áyínì]Tí a ṣe nínú òtítọ́ àti ìdúróṣánṣán.+
פ [Péè]
9 Ìtúnràpadà ni òun ti fi ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn rẹ̀,+
צ [Sádì]Ó ti pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
ק [Kófì]Mímọ́ àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ni orúkọ rẹ̀.+
ר [Réṣì]
10 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.+
ש [Sínì]Gbogbo àwọn tí ń pa wọ́n mọ́ ní ìjìnlẹ̀ òye rere.+
ת [Tọ́ọ̀]Ìyìn rẹ̀ dúró títí láé.+

