Sáàmù 106:1-48
106 Ẹ yin Jáà!+Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere;+Nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
2 Ta ní lè sọ àwọn iṣẹ́ agbára ńlá Jèhófà jáde,+Tàbí tí ó lè mú kí a gbọ́ gbogbo ìyìn rẹ̀?+
3 Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa ìdájọ́ òdodo mọ́,+Àwọn tí ń ṣe òdodo ní gbogbo ìgbà.+
4 Jèhófà, fi ìfẹ́ rere rẹ sí àwọn ènìyàn rẹ rántí mi.+Fi ìgbàlà rẹ tọ́jú mi,+
5 Kí n lè rí oore tí a ṣe sí àwọn àyànfẹ́ rẹ,+Kí n lè máa yọ̀ nínú ayọ̀ yíyọ̀ orílẹ̀-èdè rẹ,+Kí n lè máa ṣògo pẹ̀lú ogún rẹ.+
6 Àwa ti ṣẹ̀ bí ti àwọn baba ńlá wa;+Àwa ti ṣe àìtọ́; àwa ti ṣe burúkú.+
7 Ní ti àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì,Wọn kò fi ìjìnlẹ̀ òye kankan hàn nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+Wọn kò rántí ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ tí ó tóbi lọ́lá,+Ṣùgbọ́n wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní òkun, lẹ́bàá Òkun Pupa.+
8 Ó sì tẹ̀ síwájú láti gbà wọ́n là nítorí orúkọ rẹ̀,+Kí ó lè sọ agbára ńlá rẹ̀ di mímọ̀.+
9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó bá Òkun Pupa wí lọ́nà mímúná, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó gbẹ táútáú;+Ó sì mú wọn rìn gba ibú omi kọjá bí ẹní gba aginjù kọjá;+
10 Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà wọ́n là lọ́wọ́ olùkórìíra,+Ó sì tún wọn gbà padà lọ́wọ́ ọ̀tá.+
11 Omi sì bo àwọn elénìní wọn;+Ìkankan lára wọn kò ṣẹ́ kù.+
12 Nígbà náà ni wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀;+Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn rẹ̀.+
13 Kíákíá ni wọ́n gbàgbé àwọn iṣẹ́ rẹ̀;+Wọn kò dúró de ìmọ̀ràn rẹ̀.+
14 Ṣùgbọ́n wọ́n fi ìfẹ́-ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan wọn hàn ní aginjù,+Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dán Ọlọ́run wò ní aṣálẹ̀.+
15 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè,+Ó sì rán òkùnrùn amúnijoro sínú ọkàn wọn.+
16 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara Mósè ní ibùdó,+Àní Áárónì, ẹni mímọ́ Jèhófà.+
17 Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, ó sì gbé Dátánì mì,+Ó sì bo àpéjọ Ábírámù mọ́lẹ̀.+
18 Iná kan sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ní àpéjọ wọn;+Àní ọwọ́ iná kan bẹ̀rẹ̀ sí jẹ àwọn ẹni burúkú run.+
19 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n ṣe ọmọ màlúù kan ní Hórébù,+Wọ́n sì tẹrí ba fún ère dídà,+
20 Tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ṣe pàṣípààrọ̀ ògo mi+Pẹ̀lú àwòrán akọ màlúù, tí í ṣe olùjẹ ewéko.+
21 Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà wọn,+Olùṣe àwọn ohun ńlá ní Íjíbítì,+
22 Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu ní ilẹ̀ Hámù,+Àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù ní Òkun Pupa.+
23 Díẹ̀ ló kù kí ó sọ pé kí a pa wọ́n rẹ́ ráúráú,+Ọpẹ́lọpẹ́ Mósè àyànfẹ́ rẹ̀,Tí ó dúró sí àlàfo tí ń bẹ níwájú rẹ̀,+Láti yí ìhónú rẹ̀ padà, kí ó má bàa run wọ́n.+
24 Wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú ilẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra náà;+Wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.+
25 Wọ́n sì ń ráhùn ṣáá nínú àgọ́ wọn;+Wọn kò fetí sí ohùn Jèhófà.+
26 Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè nínú ìbúra nípa wọn,+Pé òun yóò mú kí wọ́n ṣubú ní aginjù,+
27 Àti pé òun yóò mú kí àwọn ọmọ wọn ṣubú láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Àti pé òun yóò tú wọn ká sáàárín àwọn ilẹ̀.+
28 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí so ara wọn mọ́ Báálì ti Péórù,+Wọ́n sì ń jẹ ẹbọ òkú.+
29 Bí wọ́n ti ń ṣokùnfà ìmúnibínú nípasẹ̀ àwọn ìbálò wọn,+Òjòjò àrànkálẹ̀ bẹ́ sílẹ̀ wàyí láàárín wọn.+
30 Nígbà tí Fíníhásì dìde, tí ó sì dá sí i,+Nígbà náà ni òjòjò àrànkálẹ̀ náà dáwọ́ dúró.
31 A sì wá kà á sí òdodo fún unNí ìran dé ìran fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
32 Síwájú sí i, wọ́n fa ìtánni-ní-sùúrù níbi omi Mẹ́ríbà,+Tí ó fi jẹ́ pé nǹkan burú fún Mósè nítorí wọn.+
33 Nítorí pé wọ́n mú ẹ̀mí rẹ̀ korò,Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ètè rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà ìwàǹwára.+
34 Wọn kò pa àwọn ènìyàn náà rẹ́ ráúráú,+Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún wọn.+
35 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,+Wọ́n sì ń kọ́ àwọn iṣẹ́ wọn.+
36 Wọ́n sì ń sin òrìṣà wọn,+Ìwọ̀nyí sì wá jẹ́ ìdẹkùn fún wọn.+
37 Wọn a sì máa fi àwọn ọmọkùnrin wọn+Àti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù.+
38 Tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀ ṣáá,+Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn,Àwọn tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì;+Ìtàjẹ̀sílẹ̀ sì wá sọ ilẹ̀ náà di eléèérí.+
39 Wọ́n sì wá di aláìmọ́ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ wọn,+Wọ́n sì ń ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe nípasẹ̀ àwọn ìbálò wọn.+
40 Ìbínú Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sí àwọn ènìyàn rẹ̀,+Ó sì wá ṣe họ́ọ̀ sí ogún rẹ̀.+
41 Léraléra ni ó sì fi wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+Kí àwọn tí ó kórìíra wọn lè ṣàkóso lé wọn lórí,+
42 Kí àwọn ọ̀tá wọn sì lè ni wọ́n lára,Kí a sì tẹ̀ wọ́n lórí ba lábẹ́ ọwọ́ wọn.+
43 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó dá wọn nídè,+Ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn a ṣọ̀tẹ̀ nínú ipa ọ̀nà àìgbọràn wọn,+A sì rẹ̀ wọ́n wálẹ̀ nítorí ìṣìnà wọn.+
44 Òun a sì rí wàhálà wọn+Nígbà tí ó bá gbọ́ igbe ìpàrọwà wọn.+
45 Òun a sì rántí májẹ̀mú rẹ̀ sí wọn,+Òun a sì kẹ́dùn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tí ó tóbi lọ́lá.+
46 Òun a sì jẹ́ kí wọ́n di ẹni ìṣojú-àánú-síNíwájú gbogbo àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè.+
47 Gbà wá là, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa,+Kí o sì kó wa jọpọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè,+Kí a lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ,+Kí a lè máa fi ayọ̀ ńláǹlà sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ.+
48 Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì+Láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin;Kí gbogbo ènìyàn sì wí pé Àmín.+Ẹ yin Jáà!+

