Sáàmù 104:1-35

104  Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi.+Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi gan-an.+Ìwọ ti fi iyì àti ọlá ńlá wọ ara rẹ láṣọ,+   Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ bí ẹ̀wù,+O na ọ̀run bí aṣọ àgọ́,+   Ẹni tí ó fi ìtì igi kọ́ àwọn ìyẹ̀wù rẹ̀ òkè sínú omi gan-an,+Tí ó fi àwọsánmà ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+Tí ń rìn lórí ìyẹ́ apá ẹ̀fúùfù,+   Tí ó ṣe àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mí,+Tí ó sì ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní iná tí ń jẹni run.+   Ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀;+A kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.+   Ìwọ fi ibú omi tí ó rí bí ẹ̀wù bò ó.+Omi dúró lókè àwọn òkè ńlá pàápàá.+   Nítorí ìbáwí mímúná rẹ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ;+Nítorí ìró ààrá rẹ, a mú wọ́n sáré nínú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì—   Àwọn òkè ńlá bẹ̀rẹ̀ sí ròkè,+Àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀—Sí ibi tí ìwọ fi lélẹ̀ fún wọn.   Ìwọ pa ààlà, tí wọn kò gbọ́dọ̀ ré kọjá,+Pé kí wọ́n má ṣe tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.+ 10  Ó ń fi àwọn ìsun ránṣẹ́ sí àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá;+Wọ́n ń lọ láàárín àwọn òkè ńláńlá. 11  Wọ́n ń bá a lọ ní fífún gbogbo ẹranko inú pápá gbalasa ní ohun mímu;+Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà+ ń pa òùngbẹ wọn déédéé. 12  Òkè wọn ni àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run ń wọ̀ sí;+Láti àárín ẹ̀ka eléwé ṣùṣùrù ni wọ́n ti ń mú ìró jáde.+ 13  Ó ń bomi rin àwọn òkè ńláńlá láti àwọn ìyẹ̀wù rẹ̀ òkè.+Èso iṣẹ́ rẹ tẹ́ ilẹ̀ ayé lọ́rùn.+ 14  Ó ń mú kí koríko tútù rú jáde fún àwọn ẹranko,+Àti ewéko fún ìlò aráyé,+Láti mú kí oúnjẹ jáde wá láti inú ilẹ̀,+ 15  Àti wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀,+Láti mú kí òróró máa mú ojú dán,+Àti oúnjẹ tí ń gbé ọkàn-àyà ẹni kíkú ró.+ 16  Àwọn igi Jèhófà ní ìtẹ́lọ́rùn,Àwọn kédárì Lẹ́bánónì tí ó gbìn,+ 17  Níbi tí àwọn ẹyẹ tìkára wọn ń kọ́ ìtẹ́ sí.+Ní ti ẹyẹ àkọ̀, àwọn igi júnípà ni ilé rẹ̀.+ 18  Àwọn òkè ńlá+ gíga wà fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá;+Àwọn àpáta gàǹgà jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn gara orí àpáta.+ 19  Ó ṣe òṣùpá fún àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀;+Oòrùn pàápàá mọ ibi tí ó máa ń wọ̀ sí dáadáa.+ 20  Ìwọ ń fa òkùnkùn, kí ó lè di òru;+Inú rẹ̀ ni gbogbo ẹranko ẹhànnà inú igbó ti ń rìn. 21  Àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ń ké ramúramù fún ẹran ọdẹ+Àti fún wíwá oúnjẹ wọn lọ́dọ̀ Ọlọ́run tìkára rẹ̀.+ 22  Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí ràn+—wọ́n fà sẹ́yìn,Wọ́n sì dùbúlẹ̀ sí àwọn ibi ìfarapamọ́ wọn. 23  Ènìyàn jáde lọ sẹ́nu ìgbòkègbodò rẹ̀+Àti sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí di àṣálẹ́.+ 24  Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà!+Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe.+Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.+ 25  Ní ti òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì gbòòrò gan-an,+Ibẹ̀ ni àwọn ohun tí ń rìn ká wà láìníye,+Àwọn ẹ̀dá alààyè, èyí tí ó kéré àti èyí tí ó tóbi.+ 26  Ibẹ̀ ni àwọn ọkọ̀ òkun ń lọ;+Ní ti Léfíátánì,+ òun ni ìwọ ṣẹ̀dá kí ó máa ṣeré kiri nínú rẹ̀.+ 27  Gbogbo wọn—ìwọ ni wọ́n ń dúró dè+Láti máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò rẹ̀.+ 28  Ohun tí o fi fún wọn ni wọ́n ń kó.+Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ—wọ́n sì ní ìtẹ́lọ́rùn ní ti àwọn ohun rere.+ 29  Bí ìwọ bá fi ojú rẹ pa mọ́, ìyọlẹ́nu a dé bá wọn.+Bí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn kúrò, wọn a gbẹ́mìí mì,+Wọn a sì padà lọ sínú ekuru wọn.+ 30  Bí ìwọ bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a óò dá wọn;+Ìwọ a sì sọ ojú ilẹ̀ di tuntun. 31  Ògo Jèhófà yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+Jèhófà yóò máa yọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀.+ 32  Ó ń wo ilẹ̀ ayé, ilẹ̀ ayé sì wárìrì;+Ó fọwọ́ kan àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ń rú èéfín.+ 33  Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé mi;+Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run mi níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà.+ 34  Kí ìrònújinlẹ̀ mi nípa rẹ̀ dùn mọ́ni.+Èmi, ní tèmi, yóò máa yọ̀ nínú Jèhófà.+ 35  Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò pa rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé;+Àti ní ti àwọn ẹni burúkú, wọn kò ní sí mọ́.+Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi. Ẹ yin Jáà!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé