Sáàmù 103:1-22
Ti Dáfídì.
103 Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi,+Àní ohun gbogbo tí ń bẹ nínú mi, fi ìbùkún fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.+
2 Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi,Má sì gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀,+
3 Ẹni tí ń dárí gbogbo ìṣìnà rẹ jì,+Ẹni tí ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn,+
4 Ẹni tí ń gba ìwàláàyè rẹ padà kúrò nínú kòtò,+Ẹni tí ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú dé ọ ládé,+
5 Ẹni tí ń fi ohun rere tẹ́ ọ lọ́rùn ní ìgbà ayé rẹ;+Ìgbà èwe rẹ ń sọ ara rẹ̀ dọ̀tun gẹ́gẹ́ bí ti idì.+
6 Jèhófà ń mú àwọn ìṣe òdodo ṣẹ ní kíkún+Àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ń lù ní jìbìtì.+
7 Ó sọ àwọn ọ̀nà rẹ̀ di mímọ̀ fún Mósè,+Àní ìbálò rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
8 Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́,+Ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.+
9 Òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo,+Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+
10 Òun kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa;+Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa.+
11 Nítorí pé bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé,+Bẹ́ẹ̀ ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+
12 Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn,+Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa.+
13 Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀,+Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.+
14 Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa,+Ó rántí pé ekuru ni wá.+
15 Ní ti ẹni kíkú, àwọn ọjọ́ rẹ̀ dà bí ti koríko tútù;+Bí ìtànná orí pápá ni bí ó ṣe ń yọ ìtànná.+
16 Nítorí pé ẹ̀fúùfù lásán yóò fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, kò sì sí mọ́;+Ipò rẹ̀ kì yóò sì mọ̀ ọ́n mọ́.+
17 Ṣùgbọ́n inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà jẹ́ láti àkókò tí ó lọ kánrin àní dé àkókò tí ó lọ kánrin+Sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+Àti òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ-ọmọ,+
18 Sí àwọn tí ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́+Àti sí àwọn tí ó rántí àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ̀ láti máa pa wọ́n mọ́.+
19 Jèhófà tìkára rẹ̀ ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọ̀run gan-an;+Àkóso rẹ̀ sì ń jọba lórí ohun gbogbo.+
20 Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì+ rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́,+Nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀.+
21 Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀,+Ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.+
22 Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin iṣẹ́ rẹ̀,+Ní gbogbo ibi tí ó ń jọba lé.+Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi.+

