Sáàmù 102:1-28
Àdúrà ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó di ahẹrẹpẹ, tí ó sì tú ìdàníyàn rẹ̀ jáde níwájú Jèhófà tìkára rẹ̀.+
102 Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;+Ọ̀dọ̀ rẹ sì ni kí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ wá.+
2 Má fi ojú rẹ pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí mo bá wà nínú hílàhílo.+Dẹ etí sí mi;+Ní ọjọ́ tí mo bá pè, ṣe wéré, dá mi lóhùn.+
3 Nítorí pé àwọn ọjọ́ mi ti wá sí òpin gẹ́gẹ́ bí èéfín,+Àní egungun mi ni a ti mú kí ó gbóná yoyo gẹ́gẹ́ bí ibi ìdáná.+
4 Ọkàn-àyà mi ni a ti kọlù gẹ́gẹ́ bí ewéko, ó sì gbẹ dànù,+Nítorí pé mo ti gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.+
5 Nítorí ìró ìmí ẹ̀dùn mi,+Egungun mi ti lẹ̀ mọ́ ẹran ara mi.+
6 Mo jọ ẹyẹ òfú tí ń bẹ ní aginjù.+Mo dà bí òwìwí kékeré tí ń bẹ ní àwọn ibi ahoro.
7 Mo ti rù hangogo,Mo sì dà bí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.+
8 Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí.+Àwọn tí ń mú kí n ṣe bí òmùgọ̀ ti fi èmi pàápàá búra.+
9 Nítorí pé mo ti jẹ eérú bí ẹní jẹ oúnjẹ;+Àwọn ohun tí mo ń mu ni mo sì ti da ẹkún pàápàá pọ̀ mọ́,+
10 Nítorí ìdálẹ́bi rẹ àti ìkannú rẹ;+Nítorí pé ìwọ ti gbé mi sókè, kí o lè sọ mí nù.+
11 Àwọn ọjọ́ mi dà bí òjìji tí ń pa rẹ́ lọ,+Èmi alára sì gbẹ dànù bí ewéko lásán-làsàn.+
12 Ní tìrẹ, Jèhófà, ìwọ yóò máa gbé fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Ìrántí rẹ yóò sì máa wà ní ìran dé ìran.+
13 Ìwọ tìkára rẹ yóò dìde, ìwọ yóò ṣàánú fún Síónì,+Nítorí pé ó jẹ́ àsìkò láti ṣe ojú rere sí i,Nítorí pé àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti dé.+
14 Nítorí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní ìdùnnú sí àwọn òkúta rẹ̀,+Wọ́n sì yí ojú rere wọn sí ekuru rẹ̀.+
15 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà,+ Gbogbo ọba ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù ògo rẹ.+
16 Nítorí ó dájú pé Jèhófà yóò gbé Síónì ró;+Òun yóò fara hàn nínú ògo rẹ̀.+
17 Ó dájú pé òun yóò yíjú sí àdúrà àwọn tí a kó gbogbo nǹkan ìní wọn lọ,+Kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àdúrà wọn.+
18 Èyí ni a kọ̀wé rẹ̀ fún ìran ẹ̀yìn ọ̀la;+Àwọn ènìyàn tí a óò dá yóò sì máa yin Jáà.+
19 Nítorí pé ó ti bojú wolẹ̀ láti ibi gíga mímọ́ rẹ̀,+Àní láti ọ̀run ni Jèhófà tìkára rẹ̀ ti wo ilẹ̀ ayé,+
20 Láti gbọ́ ìmí ẹ̀dùn ẹlẹ́wọ̀n,+Láti tú àwọn tí a yàn kalẹ̀ fún ikú;+
21 Kí a lè polongo orúkọ Jèhófà ní Síónì+Àti ìyìn rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù,+
22 Nígbà tí a bá kó gbogbo ènìyàn jọ pa pọ̀,+Àti àwọn ìjọba láti máa sin Jèhófà.+
23 Ó ṣẹ́ agbára mi níṣẹ̀ẹ́ lójú ọ̀nà,+Ó ké àwọn ọjọ́ mi kúrú.+
24 Mo sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi,Má ṣe mú mi kúrò ní ààbọ̀ àwọn ọjọ́ mi;+Jálẹ̀jálẹ̀ ìran-ìran ni àwọn ọdún rẹ.+
25 Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,+Ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+
26 Àwọn tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó;+Àti gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, gbogbo wọn yóò gbó.+Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò pààrọ̀ wọn, wọn yóò sì lo ìgbà wọn parí.+
27 Ṣùgbọ́n bákan náà ni ìwọ wà, àwọn ọdún rẹ kì yóò sì parí.+
28 Ọmọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò máa wà láàyè nìṣó;+A ó sì fìdí àwọn ọmọ wọn múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in níwájú rẹ.”+

