Sáàmù 101:1-8
Ti Dáfídì. Orin atunilára.
101 Ṣe ni èmi yóò máa kọrin nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìdájọ́.+Ìwọ, Jèhófà, ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí.+
2 Ṣe ni èmi yóò máa fi ọgbọ́n inú hùwà lọ́nà àìlálèébù.+Ìgbà wo ni ìwọ yóò tọ̀ mí wá?+Èmi yóò máa rìn káàkiri nínú ìwà títọ́ ọkàn-àyà mi nínú ilé mi.+
3 Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.+Èmi kórìíra ìgbòkègbodò àwọn tí ó ti yapa;+Kì í dìrọ̀ mọ́ mi.+
4 Ọkàn-àyà wíwọ́ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi;+Èmi kò mọ ohun búburú kankan.+
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fọ̀rọ̀ èké ba alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ jẹ́ ní ìkọ̀kọ̀,+Òun ni èmi ń pa lẹ́nu mọ́.+Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ojú ìrera àti ọkàn-àyà ìṣefọ́ńté,+Òun ni èmi kò lè fara dà.+
6 Ojú mi ń bẹ lára àwọn olùṣòtítọ́ ilẹ̀ ayé,+Kí wọ́n lè máa bá mi gbé.+Ẹni tí ń rìn lọ́nà àìlálèébù,+Òun ni yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi.+
7 Kò sí oníṣẹ́ àgálámàṣà tí yóò máa gbé inú ilé mi.+Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣèké, òun kì yóò fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in+Ní iwájú mi.+
8 Òròòwúrọ̀ ni èmi yóò máa pa gbogbo àwọn ẹni burúkú ilẹ̀ ayé lẹ́nu mọ́,+Láti ké gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́+ kúrò nínú ìlú ńlá+ Jèhófà.

