Sáàmù 100:1-5
Orin atunilára ti ìdúpẹ́.+
100 Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.+
2 Ẹ fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà.+Ẹ fi igbe ìdùnnú wọlé wá síwájú rẹ̀.+
3 Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run.+Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.+Àwa ni ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá ìjẹko rẹ̀.+
4 Ẹ wá sí àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìdúpẹ́,+Sínú àwọn àgbàlá rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìyìn.+Ẹ fi ọpẹ́ fún un, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀.+
5 Nítorí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere;+Inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Àti ìṣòtítọ́ rẹ̀ láti ìran dé ìran.+

