Sáàmù 10:1-18
ל [Lámédì]
10 Jèhófà, èé ṣe tí ìwọ fi dúró lókèèrè réré?+Èé ṣe tí ìwọ fi ara rẹ pa mọ́ ní àwọn àkókò wàhálà?+
2 Nínú ìrera rẹ̀, kíkankíkan ni ẹni burúkú ń lépa ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́;+A mú wọn nípasẹ̀ àwọn èrò-ọkàn tí wọ́n ti gbìrò.+
3 Nítorí pé ẹni burúkú ti yin ara rẹ̀ nítorí ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan ti ọkàn rẹ̀,+Ẹni tí ń jẹ èrè àìyẹ+ sì ti súre fún ara rẹ̀;נ [Núnì]Kò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà.+
4 Ẹni burúkú, gẹ́gẹ́ bí ìruga rẹ̀, kò ṣe ìwádìí kankan;+Gbogbo èrò-ọkàn rẹ̀ ni pé: “Kò sí Ọlọ́run.”+
5 Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń láásìkí ní gbogbo ìgbà.+Àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ ga sókè ré kọjá sàkáání rẹ̀;+Ní ti gbogbo àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí i, ó ń wú fùkẹ̀ sí wọn.+
6 Ó wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “A kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n;+Láti ìran dé ìran, èmi yóò jẹ́ ẹni tí kò sí nínú ìyọnu àjálù kankan.”+
פ [Péè]
7 Ẹnu rẹ̀ kún fún ìbúra àti fún ẹ̀tàn àti fún ìnilára.+Ìjàngbọ̀n àti ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.+
8 Ó jókòó ní ibùba àwọn ibi ìtẹ̀dó;Àwọn ibi tí ó lùmọ́ ni yóò ti pa aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.+
ע [Áyínì]Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ aláìrìnnàkore lójú méjèèjì.+
9 Ó ń lúgọ sí ibi tí ó lùmọ́ bí kìnnìún ní ibi kọ́lọ́fín rẹ̀.+Ó ń lúgọ+ láti fipá gbé ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ lọ.Ó ń fipá gbé ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ lọ nígbà tí ó bá fa àwọ̀n rẹ̀ dí.+
10 A tẹ̀ ẹ́ rẹ́, ó tẹrí ba,Ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn tí ó dorí kodò yóò sì wá bọ́ sínú àwọn èékánná rẹ̀ lílágbára.+
11 Ó wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé:+ “Ọlọ́run ti gbàgbé.+Ó ti fi ojú rẹ̀ pa mọ́.+Dájúdájú, òun kì yóò rí i láé.”+
ק [Kófì]
12 Dìde,+ Jèhófà. Ọlọ́run, gbé ọwọ́ rẹ sókè.+Má gbàgbé àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+
13 Èé ṣe tí ẹni burúkú kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run?+Ó wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: “Ìwọ kì yóò béèrè fún ìjíhìn.”+
ר [Réṣì]
14 Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ ti rí ìjàngbọ̀n àti pákáǹleke.Ìwọ ń wò, kí o lè fi wọ́n lé ọwọ́ ara rẹ.+Ìwọ ni aláìrìnnàkore,+ ọmọdékùnrin aláìníbaba, fi ara rẹ̀ lé lọ́wọ́.Ìwọ tìkára rẹ ti di olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.+
ש [Ṣínì]
15 Ṣẹ́ apá ẹni burúkú àti ẹni búburú.+Kí o máa wá ìwà burúkú rẹ̀ títí ìwọ kì yóò fi rí i mọ́.+
16 Jèhófà ni Ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+Àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.+
ת [Tọ́ọ̀]
17 Ìwọ, Jèhófà, yóò gbọ́ ìfẹ́-ọkàn àwọn ọlọ́kàn tútù dájúdájú.+Ìwọ yóò múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀.+Ìwọ yóò dẹ etí sílẹ̀,+
18 Láti ṣe ìdájọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba àti ẹni tí a ni lára,+Kí ẹni kíkú tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ má bàa máa fa ìwárìrì mọ́.+

