Rúùtù 2:1-23

2  Wàyí o, Náómì ní ẹbí ọkùnrin,+ tí ó jẹ́ ti ọkọ rẹ̀, ọkùnrin kan tí ọlà rẹ̀ yamùrá,+ láti ìdílé Élímélékì, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Bóásì.+  Nígbà tí ó ṣe, Rúùtù obìnrin ará Móábù wí fún Náómì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí pápá, kí n sì pèéṣẹ́+ lára ṣírí ọkà ní títẹ̀lé ẹnì yòówù kí ó jẹ́ tí mo bá lè rí ojú rere lójú rẹ̀.” Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Lọ, ọmọbìnrin mi.”  Látàrí ìyẹn, ó lọ, ó sì wọ inú pápá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pèéṣẹ́ lẹ́yìn àwọn olùkórè.+ Nípa báyìí, ó ṣàdédé dé orí abá pápá tí ó jẹ́ ti Bóásì,+ tí ó wá láti ìdílé Élímélékì.+  Sì wò ó! Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn olùkórè náà pé: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín.”+ Ẹ̀wẹ̀, wọ́n wí fún un pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ.”+  Lẹ́yìn náà, Bóásì+ sọ fún ọ̀dọ́kùnrin tí a yàn ṣolórí àwọn olùkórè pé: “Ti ta ni ọ̀dọ́bìnrin yìí jẹ́?”  Nítorí náà, ọ̀dọ́kùnrin tí a yàn lé àwọn olùkórè lórí dáhùn pé: “Ọ̀dọ́bìnrin náà jẹ́ ọmọbìnrin Móábù,+ tí ó bá Náómì padà láti pápá Móábù.+  Ọmọbìnrin náà sì wí pé, ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n pèéṣẹ́,+ lára àwọn ṣírí ọkà tí a ké kúrò tí ó wà lẹ́yìn àwọn olùkórè ni èmi yóò ti kó jọ.’ Bẹ́ẹ̀ ni ó wọ inú pápá, ó sì wà lórí ìdúró láti ìgbà yẹn ní òwúrọ̀ títí di ìsinsìnyí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jókòó nínú ilé fún ìgbà díẹ̀.”+  Lẹ́yìn náà, Bóásì sọ fún Rúùtù pé: “O ti gbọ́, àbí o kò gbọ́, ọmọbìnrin mi? Má lọ pèéṣẹ́ nínú pápá mìíràn,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ kọjá ibí yìí pẹ̀lú, nípa báyìí, kí ìwọ sì rìn sún mọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin mi.+  Kí ojú rẹ máa wo pápá tí wọn yóò kórè, àwọn sì ni kí o máa bá lọ. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin láti má ṣe fọwọ́ kàn+ ọ́? Nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹ ọ́, kí o lọ síbi àwọn ohun èlò, kí o sì mu nínú èyí tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin bá pọn.”+ 10  Látàrí ìyẹn, ó dojú bolẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀,+ ó sì wí fún un pé: “Báwo ni ó ti jẹ́ tí mo fi rí ojú rere lójú rẹ, tí a fi ṣàkíyèsí mi, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè?”+ 11  Nígbà náà ni Bóásì dáhùn, ó sì wí fún un pé: “A ròyìn+ fún mi ní kíkún nípa gbogbo ohun tí o ṣe fún ìyá ọkọ rẹ lẹ́yìn ikú ọkọ+ rẹ, àti bí o ṣe tẹ̀ síwájú láti fi baba rẹ àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ àwọn ìbátan rẹ sílẹ̀, tí o sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀.+ 12  Kí Jèhófà san ọ́ lẹ́san fún bí o ṣe hùwà,+ kí owó ọ̀yà+ pípé sì wà fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lábẹ́ ìyẹ́ apá ẹni tí ìwọ wá láti wá ìsádi.”+ 13  Ó fèsì pé: “Jẹ́ kí n rí ojú rere lójú rẹ, olúwa mi, nítorí o ti tù mí nínú, àti nítorí o ti sọ̀rọ̀ fún ìránṣẹ́bìnrin+ rẹ lọ́nà tí ń finilọ́kàn-balẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, èmi alára lè má dà bí ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ rẹ.” 14  Bóásì sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún un ní àkókò oúnjẹ pé: “Sún mọ́ ìhín, kí o sì jẹ lára oúnjẹ,+ kí o sì tẹ èyí tí o bù bọ inú ọtí kíkan.” Nítorí náà, ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olùkórè, ọkùnrin náà a sì na àyangbẹ ọkà+ sí i, òun a sì jẹ, tí ó fi jẹ́ pé ó yó, tí ó sì tilẹ̀ tún ṣẹ́ nǹkan kù. 15  Lẹ́yìn náà, ó dìde láti pèéṣẹ́.+ Wàyí o, Bóásì pàṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí ó pèéṣẹ́ pẹ̀lú láàárín àwọn ṣírí ọkà tí a ké kúrò, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fìtínà+ rẹ̀. 16  Kí ẹ sì rí i dájú pẹ̀lú pé ẹ yọ díẹ̀ sílẹ̀ fún un nínú ìdì ṣírí náà, kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ sẹ́yìn, kí ó lè pèéṣẹ́ wọn,+ kí ẹ má sì bá a wí.” 17  Ó sì ń bá a lọ láti pèéṣẹ́ nínú pápá títí di ìrọ̀lẹ́,+ lẹ́yìn èyí, ó lu+ ohun tí ó ti pèéṣẹ́, ó sì wá jẹ́ nǹkan bí òṣùwọ̀n eéfà+ kan ọkà bálì. 18  Lẹ́yìn náà, ó gbé e, ó sì lọ sínú ìlú ńlá, ìyá ọkọ rẹ̀ sì rí ohun tí ó pèéṣẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ó kó oúnjẹ tí ó ṣẹ́ kù+ nígbà tí ó tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn tán jáde, ó sì fi í fún un. 19  Ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un wàyí pé: “Ibo ni o ti pèéṣẹ́ lónìí, ibo sì ni o ti ṣiṣẹ́? Kí ẹni tí ó kíyè sí ọ di alábùkún.”+ Nítorí náà, ó sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí òun ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀; ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Bóásì ni orúkọ ọkùnrin tí mo ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí.” 20  Látàrí ìyẹn, Náómì sọ fún aya ọmọ rẹ̀ pé: “Ìbùkún ni fún un láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ẹni tí kò dẹ́kun inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́+ sí àwọn alààyè àti àwọn òkú.”+ Náómì sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Ọkùnrin náà bá wa tan.+ Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùtúnnirà wa.”+ 21  Nígbà náà ni Rúùtù ọmọbìnrin Móábù wí pé: “Ó tún wí fún mi pé, ‘Nítòsí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ tèmi ni kí o wà títí di ìgbà tí wọn yóò parí gbogbo ìkórè tí mo ní.’”+ 22  Nítorí náà, Náómì+ sọ fún Rúùtù aya ọmọ rẹ̀+ pé: “Ó sàn, ọmọbìnrin mi, pé kí o bá àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ jáde, kí wọ́n má bàa mú inú bí ọ nínú pápá+ mìíràn.” 23  Ó sì ń bá a lọ ní rírìn sún mọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin Bóásì láti máa pèéṣẹ́ títí di ìgbà tí ìkórè ọkà bálì+ àti ìkórè àlìkámà fi wá sí òpin. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ+ rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé