Róòmù 6:1-23
6 Nítorí náà, kí ni àwa yóò wí? Àwa yóò ha máa bá a lọ nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè di púpọ̀ gidigidi bí?+
2 Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé! Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé a kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀,+ báwo ni àwa yóò ṣe tún máa wà láàyè nìṣó nínú rẹ̀?+
3 Tàbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo wa tí a ti batisí sínú Kristi Jésù+ ni a batisí sínú ikú rẹ̀?+
4 Nítorí náà, a sin+ wá pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìbatisí wa sínú ikú rẹ̀, kí ó bàa lè jẹ́ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú nípasẹ̀ ògo Baba,+ kí àwa pẹ̀lú lè máa rìn bákan náà nínú ọ̀tun ìwàláàyè.+
5 Nítorí bí a bá ti di sísopọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ ikú rẹ̀,+ dájúdájú, a ó so wá pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú;+
6 nítorí àwa mọ̀ pé ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà wa ni a kàn mọ́gi pẹ̀lú rẹ̀,+ kí a lè sọ ara wa tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ di aláìṣiṣẹ́,+ kí a má ṣe tún máa bá a lọ ní jíjẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.+
7 Nítorí ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+
8 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí àwa bá ti kú pẹ̀lú Kristi, a gbà gbọ́ pé a óò tún wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+
9 Nítorí a mọ̀ pé Kristi, nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú,+ kò tún kú mọ́;+ ikú kò tún jẹ́ ọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.
10 Nítorí ikú tí ó kú, ni ó kú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé;+ ṣùgbọ́n ìgbésí ayé tí ó ń gbé, ni ó ń gbé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.+
11 Bákan náà pẹ̀lú ni ẹ̀yin: ẹ ka ara yín sí òkú+ ní tòótọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n alààyè+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù.
12 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa bá a lọ láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba+ nínú àwọn ara kíkú yín, tí ẹ ó fi máa ṣègbọràn sí àwọn ìfẹ́-ọkàn wọn.+
13 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe máa bá a lọ ní jíjọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀+ bí àwọn ohun ìjà àìṣòdodo,+ ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín fún Ọlọ́run bí àwọn tí ó wà láàyè+ láti inú òkú, àti àwọn ẹ̀yà ara yín pẹ̀lú fún Ọlọ́run bí àwọn ohun ìjà+ òdodo.
14 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀gá lórí yín, níwọ̀n bí ẹ kò ti sí lábẹ́ òfin+ bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.+
15 Kí ní tẹ̀ lé e? Àwa yóò ha dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí a kò sí lábẹ́ òfin+ bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí?+ Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé!
16 Ẹ kò ha mọ̀ pé bí ẹ bá ń jọ̀wọ́ ara yín fún ẹnikẹ́ni bí ẹrú láti ṣègbọràn sí i, ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i,+ yálà ti ẹ̀ṣẹ̀+ pẹ̀lú ikú níwájú+ tàbí ti ìgbọràn+ pẹ̀lú òdodo+ níwájú?
17 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n ẹ di onígbọràn láti inú ọkàn-àyà wá sí irú ẹ̀kọ́ tí a fi yín lé lọ́wọ́.+
18 Bẹ́ẹ̀ ni, níwọ̀n bí a ti dá yín sílẹ̀+ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ẹ di ẹrú+ fún òdodo.+
19 Èmi ń sọ̀rọ̀ ní ìsọ̀rọ̀ ẹ̀dá ènìyàn nítorí àìlera ẹran ara yín:+ nítorí àní gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín+ bí ẹrú fún ìwà àìmọ́+ àti ìwà àìlófin pẹ̀lú ìwà àìlófin níwájú,+ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín nísinsìnyí bí ẹrú fún òdodo pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́ níwájú.
20 Nítorí nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀,+ ẹ jẹ́ òmìnira ní ti òdodo.
21 Kí wá ni èso+ tí ẹ máa ń so ní àkókò yẹn? Àwọn ohun+ tí ń tì yín lójú nísinsìnyí. Nítorí òpin nǹkan wọnnì ikú ni.+
22 Àmọ́ ṣá o, nísinsìnyí, nítorí pé a ti dá yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ ti di ẹrú fún Ọlọ́run,+ ẹ ń so èso+ yín lọ́nà ìjẹ́mímọ́, ìyè àìnípẹ̀kun sì ni òpin rẹ̀.+
23 Nítorí owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,+ ṣùgbọ́n ẹ̀bùn+ tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun+ nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.+

