Róòmù 15:1-33

15  Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun,+ kí a má sì máa ṣe bí ó ti wù wá.+  Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró.+  Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀;+ ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ti ṣubú lù mí.”+  Nítorí gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ+ fún ìtọ́ni+ wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà+ wa àti nípasẹ̀ ìtùnú+ láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.+  Wàyí o, kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú+ kan náà tí Kristi Jésù ní,  pé pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan,+ kí ẹ lè fi ẹnu kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.  Nítorí náà, ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kìíní-kejì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá,+ pẹ̀lú ògo fún Ọlọ́run ní iwájú.  Nítorí mo wí pé Kristi ní ti gidi di òjíṣẹ́+ àwọn tí ó dádọ̀dọ́+ nítorí jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́,+ kí ó bàa lè fìdí ìlérí+ tí Ó ṣe fún àwọn baba ńlá wọn múlẹ̀, 9  àti kí àwọn orílẹ̀-èdè+ bàa lè yin Ọlọ́run lógo fún àánú rẹ̀.+ Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Dájúdájú, ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi jẹ́wọ́ rẹ ní gbangba láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ṣe ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ.”+ 10  Ó sì tún wí pé: “Ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”+ 11  Àti pẹ̀lú: “Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ sì jẹ́ kí gbogbo àwọn ènìyàn yìn ín.”+ 12  Aísáyà sì tún wí pé: “Gbòǹgbò Jésè yóò wà,+ ẹnì kan tí ń dìde láti ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì wà;+ òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbé ìrètí wọn kà.”+ 13  Kí Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí fi ìdùnnú àti àlàáfíà gbogbo kún inú yín nípa gbígbàgbọ́ yín, kí ẹ lè ní ìrètí púpọ̀ gidigidi pẹ̀lú agbára ẹ̀mí mímọ́.+ 14  Wàyí o, èmi fúnra mi pẹ̀lú gbà nípa yín, ẹ̀yin ará mi, pé ẹ̀yin fúnra yín kún fún ìwà rere pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti kún fún ìmọ̀ gbogbo,+ àti pé ẹ̀yin pẹ̀lú lè ṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì.+ 15  Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ń kọ̀wé sí yín lọ́nà tí ó túbọ̀ jẹ́ ti àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ lórí àwọn kókó kan, bí ẹní tún ń rán yín létí,+ nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ 16  kí èmi lè jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn fún Kristi Jésù sí àwọn orílẹ̀-èdè,+ tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere+ Ọlọ́run, kí ọrẹ ẹbọ náà,+ èyíinì ni, orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, lè já sí ìtẹ́wọ́gbà,+ bí a ti ń fi ẹ̀mí mímọ́+ sọ ọ́ di mímọ́. 17  Nítorí náà, mo ní ìdí fún yíyọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Kristi Jésù+ nígbà tí ó bá kan àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ Ọlọ́run.+ 18  Nítorí pé èmi kì yóò dágbá lé àtisọ ohun kan tí kì í bá ṣe lára àwọn ohun tí Kristi ṣe nípasẹ̀ mi+ kí àwọn orílẹ̀-èdè lè jẹ́ onígbọràn,+ nípa ọ̀rọ̀+ àti ìṣe mi, 19  pẹ̀lú agbára àwọn iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu,+ pẹ̀lú agbára ẹ̀mí mímọ́; tí ó fi jẹ́ pé láti Jerúsálẹ́mù àti ní àlọyíká+ títí dé Ílíríkónì ni mo ti wàásù ìhìn rere nípa Kristi kúnnákúnná.+ 20  Lọ́nà yìí, ní tòótọ́, mo fi í ṣe ìfojúsùn mi láti má ṣe polongo ìhìn rere níbi tí a bá ti dárúkọ Kristi tẹ́lẹ̀, kí èmi má bàa máa kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ ènìyàn mìíràn;+ 21  ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Àwọn tí a kò tíì ṣe ìkéde kankan fún nípa rẹ̀ yóò rí i, àwọn tí kò sì tíì gbọ́ yóò lóye.”+ 22  Fún ìdí yìí pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ti dí mi lọ́wọ́ láti dé ọ̀dọ̀ yín.+ 23  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí èmi kò ní ìpínlẹ̀ tí a kò tíì fọwọ́ kàn mọ́ ní ẹkùn ilẹ̀ wọ̀nyí, tí mo sì ti ń ní ìyánhànhàn fún àwọn ọdún díẹ̀ láti dé ọ̀dọ̀ yín+ 24  nígbàkigbà tí mo bá wà ní ọ̀nà mi lọ sí Sípéènì,+ mo ní ìrètí, lékè ohun gbogbo, nígbà tí mo bá wà lẹ́nu ìrìn àjò sí ibẹ̀, láti rí yín fẹ̀rẹ̀, kí ẹ sì sìn+ mí díẹ̀ lọ́nà ibẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá ti kọ́kọ́ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ yín dé ìwọ̀n kan. 25  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo máa tó rin ìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+ 26  Nítorí àwọn tí ń bẹ ní Makedóníà àti Ákáyà+ ni ó ti dùn mọ́ nínú láti ṣe àjọpín àwọn nǹkan wọn nípasẹ̀ ọrẹ+ fún àwọn òtòṣì àwọn ẹni mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù. 27  Lóòótọ́, ó ti dùn mọ́ wọn nínú láti ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ajigbèsè sí wọn; nítorí bí àwọn orílẹ̀-èdè bá ti ṣe àjọpín nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí tí í ṣe tiwọn,+ àwọn pẹ̀lú jẹ gbèsè fífi àwọn nǹkan tí ó wà fún ẹran ara ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn wọ̀nyí ní gbangba.+ 28  Nítorí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣe èyí tán, tí mo sì ti mú èso+ yìí dé ọ̀dọ̀ wọn láìyingin, èmi yóò gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Sípéènì.+ 29  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, mo mọ̀ pé nígbà tí mo bá wá sí ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wá pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Kristi.+ 30  Wàyí o, mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹ̀mí,+ pé kí ẹ tiraka pẹ̀lú mi nínú àdúrà sí Ọlọ́run fún mi,+ 31  kí a lè dá mi nídè+ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà àti kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi tí ó wà fún Jerúsálẹ́mù+ lè já sí ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn ẹni mímọ́,+ 32  kí ó bàa lè jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú ìdùnnú nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run, a ó tù mí lára+ pa pọ̀ pẹ̀lú yín. 33  Kí Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín.+ Àmín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé