Róòmù 12:1-21
12 Nítorí náà, mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run pàrọwà fún yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara+ yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ+ ààyè,+ mímọ́,+ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà,+ iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀+ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.+
2 Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà+ ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà,+ kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín+ ìfẹ́+ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.
3 Nítorí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ;+ ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro,+ olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pín ìwọ̀n+ ìgbàgbọ́+ fún un.
4 Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti ní ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara nínú ara kan,+ ṣùgbọ́n tí gbogbo ẹ̀yà ara náà kò ní ẹ̀yà iṣẹ́ kan náà,
5 bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pọ̀, a jẹ́ ara kan+ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ṣùgbọ́n tí àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.+
6 Nígbà náà, níwọ̀n bí àwa ti ní àwọn ẹ̀bùn tí ó yàtọ̀ síra+ ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ tí a fi fún wa, ì báà ṣe àsọtẹ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa sọ tẹ́lẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí a pín fún wa níwọ̀n yíyẹ;
7 tàbí iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan, ẹ jẹ́ kí a wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí;+ tàbí ẹni tí ń kọ́ni,+ kí ó wà lẹ́nu kíkọ́ni rẹ̀;+
8 tàbí ẹni tí ń gbani níyànjú, kí ó wà lẹ́nu ìgbani-níyànjú rẹ̀;+ ẹni tí ń pín nǹkan fúnni, kí ó máa ṣe é pẹ̀lú àìṣahun;+ ẹni tí ń ṣe àbójútó,+ kí ó máa fi ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan ṣe é; ẹni tí ń fi àánú hàn,+ kí ó máa fi ọ̀yàyà ṣe é.
9 Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́+ yín wà láìsí àgàbàgebè.+ Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú,+ ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.+
10 Nínú ìfẹ́ ará,+ ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá+ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.
11 Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín.+ Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín.+ Ẹ máa sìnrú fún Jèhófà.+
12 Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí.+ Ẹ máa ní ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú.+ Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.+
13 Ẹ máa ṣe àjọpín pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn.+ Ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.+
14 Ẹ máa bá a nìṣó ní sísúre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni;+ ẹ máa súre,+ ẹ má sì máa gégùn-ún.+
15 Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀;+ ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.
16 Irú èrò inú kan náà tí ẹ ní sí ara yín ni kí ẹ ní sí àwọn ẹlòmíràn;+ ẹ má ṣe máa gbé èrò inú yín ka àwọn ohun gíga fíofío,+ ṣùgbọ́n kí a máa ṣamọ̀nà yín lọ pẹ̀lú àwọn ohun rírẹlẹ̀.+ Ẹ má ṣe jẹ́ olóye ní ojú ara yín.+
17 Ẹ má ṣe fi ibi san ibi+ fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn.
18 Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà+ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.
19 Ẹ má ṣe gbẹ̀san+ ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú;+ nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.”+
20 Ṣùgbọ́n, “bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu;+ nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò máa kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí.”+
21 Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.+

