Orin Sólómọ́nì 8:1-14

8  “Ì bá ṣe pé ìwọ dà bí arákùnrin mi,+ tí ó mu ọmú ìyá mi!+ Èmi ì bá rí ọ lóde, èmi ì bá fi ẹnu kò ọ́ lẹ́nu.+ Àwọn ènìyàn kò tilẹ̀ ní tẹ́ńbẹ́lú mi.  Èmi ì bá ṣamọ̀nà rẹ, èmi ì bá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi,+ ẹni tí ó ti máa ń kọ́ mi. Èmi ì bá fún ọ ní wáìnì+ mu, èyí tí a fi èròjà atasánsán sí, àṣẹ̀ṣẹ̀fún omi èso pómégíránétì.  Ọwọ́ òsì rẹ̀ ì bá wà lábẹ́ orí mi; àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀—ì bá gbá mi mọ́ra.+  “Mo ti mú kí ẹ wá sábẹ́ ìbúra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, pé kí ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.”+  “Ta ni obìnrin yìí+ tí ń jáde bọ̀ láti aginjù,+ tí ó fara ti olólùfẹ́ rẹ̀?”+ “Abẹ́ igi ápù ni mo ti ru ọ́ sókè. Ibẹ̀ ni ìyá rẹ ti wà nínú ìroragógó ìbímọ nítorí rẹ. Ibẹ̀ ni ẹni tí ó bí ọ ti ní ìroragógó ìbímọ.+  “Gbé mi lé ọkàn-àyà rẹ gẹ́gẹ́ bí èdìdì,+ gẹ́gẹ́ bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí pé ìfẹ́ lágbára bí ikú,+ ìfidandanlé ìfọkànsìn+ tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe sì jẹ́ aláìjuwọ́sílẹ̀ bí Ṣìọ́ọ̀lù. Jíjó rẹ̀ jẹ́ jíjó iná, ọwọ́ iná Jáà.+  Omi púpọ̀ pàápàá kò lè paná ìfẹ́,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn odò alára kò lè gbé e lọ.+ Bí ọkùnrin kan yóò bá fi gbogbo àwọn ohun tí ó níye lórí nínú ilé rẹ̀ fún ìfẹ́, dájúdájú àwọn ènìyàn yóò tẹ́ńbẹ́lú wọn.”  “Àwa ní arábìnrin+ kékeré kan tí kò ní ọmú rárá. Kí ni a ó ṣe fún arábìnrin wa ní ọjọ́ tí a ó tọrọ rẹ̀?”  “Bí òun bá jẹ́ ògiri,+ a ó mọ odi orí òrùlé tí ó jẹ́ fàdákà lé e lórí; ṣùgbọ́n bí òun bá jẹ́ ilẹ̀kùn,+ a ó fi pátákó kédárì dí i pa.” 10  “Ògiri ni mí, ọmú mi sì dà bí ilé gogoro.+ Nínú ọ̀ràn yìí, lójú rẹ̀ mo dà bí ẹni tí ó rí àlàáfíà. 11  “Ọgbà àjàrà+ kan wà tí ó jẹ́ ti Sólómọ́nì ní Baali-hámọ́nì. Ó fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn olùtọ́jú.+ Olúkúlùkù a máa mú ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà wá fún èso rẹ̀. 12  “Ọgbà àjàrà mi, tí ó jẹ́ tèmi, wà ní ìkáwọ́ mi. Ẹgbẹ̀rún ni tìrẹ, ìwọ Sólómọ́nì, igba sì ni ti àwọn tí ń tọ́jú èso rẹ̀.” 13  “Ìwọ tí ń gbé inú àwọn ọgbà,+ àwọn alájọṣe ń fetí sí ohùn rẹ. Jẹ́ kí n gbọ́ ọ.”+ 14  “Fẹsẹ̀ fẹ, olólùfẹ́ mi, sì ṣe ara rẹ bí àgbàlàǹgbó tàbí ọmọ akọ àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè ńláńlá ti èròjà atasánsán.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé