Orin Sólómọ́nì 7:1-13
7 “Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ mà lẹ́wà nínú sálúbàtà+ rẹ o, ìwọ ọmọbìnrin ọlọ́kàn ìmúratán!+ Ìyọlẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ itan rẹ dà bí àwọn ohun ọ̀ṣọ́,+ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà.
2 Ìdodo rẹ jẹ́ àwokòtò róbótó. Má ṣe jẹ́ kí ó ṣaláìní àdàlù wáìnì.+ Ikùn rẹ jẹ́ òkìtì àlìkámà, tí a fi àwọn òdòdó lílì+ ṣe ọgbà yí ká.
3 Ọmú rẹ méjèèjì dà bí ọmọ méjì, ìbejì abo àgbàlàǹgbó.+
4 Ọrùn+ rẹ dà bí ilé gogoro eyín erin. Ojú+ rẹ dà bí odò adágún ní Hẹ́ṣíbónì,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè Bati-rábímù. Imú rẹ dà bí ilé gogoro Lẹ́bánónì, tí ó dojú kọ Damásíkù.
5 Orí rẹ lára rẹ dà bí Kámẹ́lì,+ àwọn jọ̀lọ̀mì+ irun orí rẹ sì dà bí irun àgùntàn tí a fi àwọ̀ àlùkò àdàpọ̀-mọ́-pupa pa láró.+ Ìṣànwálẹ̀ rẹ̀ gbé ọba dè.+
6 O mà lẹ́wà o, o mà wuni o, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láàárín àwọn ohun tí ń mú inú dídùn kíkọyọyọ wá!+
7 Ìdúró rẹ yìí jọ igi+ ọ̀pẹ, ọmú+ rẹ sì jọ òṣùṣù èso déètì.+
8 Mo wí pé, ‘Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ, kí n lè di àwọn ọ̀pá èso déètì rẹ̀ mú.’ Jọ̀wọ́, kí ọmú rẹ dà bí òṣùṣù àjàrà, kí ìtasánsán imú rẹ sì dà bí àwọn èso ápù,
9 kí òkè ẹnu rẹ sì dà bí wáìnì+ tí ó dára jù lọ, èyí tí ń lọ tìnrín+ fún olólùfẹ́ mi, tí ó rọra ń ṣàn lórí ètè àwọn tí ó sùn.”
10 “Ti olólùfẹ́ mi ni èmi,+ ọ̀dọ̀ mi sì ni ọkàn rẹ̀ ń fà sí.+
11 Wá, ìwọ olólùfẹ́ mi, jẹ́ kí a jáde lọ sí pápá;+ jẹ́ kí a wọ̀ sí àárín àwọn ewéko làálì.+
12 Jẹ́ kí a dìde ní kùtùkùtù lọ sí àwọn ọgbà àjàrà, kí a lè rí i bóyá àjàrà ti rú jáde,+ bóyá ìtànná ti là,+ bóyá àwọn igi pómégíránétì ti yọ ìtànná òdòdó.+ Ibẹ̀ ni èmi yóò ti fún ọ ní àwọn ìfìfẹ́hàn mi.+
13 Àwọn máńdírékì+ pàápàá ti tú ìtasánsán wọn jáde, gbogbo onírúurú èso+ tí ó jẹ́ ààyò jù lọ sì ń bẹ lẹ́bàá àwọn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé wa. Àwọn tí ó jẹ́ tuntun àti ẹ̀gbẹ ni mo ti tò jọ pa mọ́ fún ọ, ìwọ olólùfẹ́ mi.

