Orin Sólómọ́nì 5:1-16

5  “Mo ti dé sínú ọgbà mi,+ ìwọ arábìnrin mi,+ ìyàwó+ mi. Mo ti já òjíá+ mi pa pọ̀ pẹ̀lú èròjà atasánsán mi. Mo ti jẹ afárá oyin mi pa pọ̀ pẹ̀lú oyin+ mi; mo ti mu wáìnì mi pa pọ̀ pẹ̀lú wàrà mi.” “Ẹ jẹun, ẹ̀yin alábàákẹ́gbẹ́! Ẹ mu, ẹ sì mu àwọn ìfìfẹ́hàn ní àmupara!”+ 2  “Mo sùn, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà mi jí kalẹ̀.+ Ìró ìkànkùn+ olólùfẹ́ mi nìyẹn!” “Ṣílẹ̀kùn fún mi,+ ìwọ arábìnrin mi, ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi, àdàbà mi, onítèmi aláìlẹ́gàn!+ Nítorí orí mi kún fún ìrì, àwọn ìdì irun mi sì kún fún ẹ̀kán omi òru.”+ 3  “‘Mo ti bọ́ aṣọ mi. Báwo ni mo ṣe lè gbé e wọ̀ padà? Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi. Báwo ni mo ṣe lè fi èérí yí i?’ 4  Olólùfẹ́ mi alára fa ọwọ́ sẹ́yìn kúrò lára ihò ilẹ̀kùn, ìhà inú+ mi pàápàá sì ru gùdù nínú mi. 5  Mo dìde, àní èmi, láti ṣílẹ̀kùn fún olólùfẹ́ mi, òjíá sì ń kán tótó ní ọwọ́ mi àti òjíá olómi ní àwọn ìka mi, sára àwọn ìtẹkòtò àgádágodo. 6  Mo ṣílẹ̀kùn, àní èmi, fún olólùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olólùfẹ́ mi tìkára rẹ̀ ti yíjú padà, ó ti kọjá lọ. Ọkàn mi ti jáde kúrò nínú mi nígbà tí ó sọ̀rọ̀. Mo wá a, ṣùgbọ́n n kò rí i.+ Mo pè é, ṣùgbọ́n kò dá mi lóhùn. 7  Àwọn olùṣọ́+ tí ń lọ káàkiri ní ìlú ńlá yìí rí mi. Wọ́n lù mí, wọ́n dọ́gbẹ́ sí mi lára. Àwọn olùṣọ́ ògiri+ gba aṣọ ìlékè mi gbígbòòrò kúrò lára mi. 8  “Mo ti mú kí ẹ wá sábẹ́ ìbúra,+ ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù,+ pé, bí ẹ bá rí olólùfẹ́+ mi, kí ẹ sọ fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.”+ 9  “Báwo ni olólùfẹ́ rẹ ṣe ju olólùfẹ́+ mìíràn lọ, ìwọ arẹwà jù lọ nínú àwọn obìnrin?+ Báwo ni olólùfẹ́ rẹ ṣe ju olólùfẹ́ mìíràn lọ, tí ìwọ fi mú kí a wá sábẹ́ irúfẹ́ ìbúra bí èyí?”+ 10  “Olólùfẹ́ mi ń dán gbinrin, ó sì jẹ́ apọ́nbéporẹ́, ẹni tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà jù lọ láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.+ 11  Orí rẹ̀ jẹ́ wúrà, wúrà tí a yọ́ mọ́. Àwọn ìdì irun rẹ̀ jẹ́ òṣùṣù èso déètì. Irun dúdú rẹ̀ dà bí ẹyẹ ìwò. 12  Àwọn ojú rẹ̀ dà bí àwọn àdàbà tí ó wà lẹ́bàá ipa ojú ọ̀nà omi, tí ń fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n jókòó sáàárín àwọn etí bèbè. 13  Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dà bí ebè títẹ́ fún èròjà atasánsán+ ti inú ọgbà, àwọn ilé gogoro ewéko olóòórùn dídùn. Ètè rẹ̀ jẹ́ òdòdó lílì, tí òjíá+ olómi ń kán tótó lára rẹ̀. 14  Ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òbìrípo wúrà, tí ó kún fún kírísóláítì. Inú rẹ̀ jẹ́ àwo eyín erin tí a fi àwọn sàfáyà bò. 15  Ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọwọ̀n òkúta mábílì tí a gbé ka àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ tí a fi wúrà tí a yọ́ mọ́ ṣe. Ìrísí rẹ̀ dà bí Lẹ́bánónì, ààyò bí àwọn kédárì.+ 16  Òkè ẹnu rẹ̀ jẹ́ ògédé dídùndídùn, ohun gbogbo nípa rẹ̀ sì fani lọ́kàn mọ́ra.+ Èyí ni olólùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀dọ́mọkùnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé