Oníwàásù 8:1-17

8  Ta ní ń bẹ tí ó dà bí ọlọ́gbọ́n?+ Ta ní sì ń bẹ tí ó mọ ìtumọ̀ ohun kan?+ Ọgbọ́n tí ẹnì kan ní ń mú kí ojú rẹ̀ dán, ìrorò ojú rẹ̀ pàápàá a sì yí padà sí dáadáa.+ 2  Mo ní: “Àní kí o pa àṣẹ ìtọ́ni ọba mọ́,+ ìyẹn sì jẹ́ ní tìtorí ìbúra Ọlọ́run.+ 3  Má ṣe kánjú, kí o lè jáde lọ kúrò níwájú rẹ̀.+ Má ṣe dúró nínú ohun búburú.+ Nítorí pé gbogbo ohun tí ó ní inú dídùn láti ṣe ni yóò ṣe,+ 4  nítorí pé ọ̀rọ̀ ọba ni agbára àkóso;+ ta sì ni ó lè sọ fún un pé: ‘Kí ni ìwọ ń ṣe?’” 5  Ẹni tí ń pa àṣẹ mọ́ kì yóò mọ ohun+ oníyọnu àjálù kankan, ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n yóò sì mọ ìgbà àti ìdájọ́.+ 6  Nítorí ìgbà àti ìdájọ́ wà àní fún gbogbo àlámọ̀rí,+ nítorí tí ìyọnu àjálù aráyé pọ̀ yanturu lórí wọn.+ 7  Nítorí kò sí ẹnì kankan tí ó mọ ohun tí yóò wá ṣẹlẹ̀,+ nítorí pé ta ní lè sọ fún un bí yóò ti ṣẹlẹ̀ gan-an? 8  Kò sí ènìyàn tí ó ní agbára lórí ẹ̀mí láti kó ẹ̀mí+ níjàánu; bẹ́ẹ̀ ni kò sí agbára àkóso ní ọjọ́ ikú;+ bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdásílẹ̀ èyíkéyìí nínú ogun+ náà. Ìwà burúkú kì yóò sì pèsè àsálà fún àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara wọn fún un.+ 9  Gbogbo èyí ni mo ti rí, fífi ọkàn-àyà mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn sì wà, ní àkókò tí ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe+ rẹ̀. 10  Ṣùgbọ́n, bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ti rí tí a ń sìnkú+ àwọn ẹni burúkú, bí wọ́n ṣe wọlé àti bí wọ́n ṣe máa ń lọ kúrò ní ibi+ mímọ́ tí a sì ń gbàgbé wọn ní ìlú ńlá tí wọ́n ti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.+ Asán ni èyí pẹ̀lú. 11  Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán+ mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.+ 12  Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ń ṣe búburú+ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, tí ó sì ń bá a lọ fún ìgbà pípẹ́ bí ó ti wù ú, síbẹ̀ èmi mọ̀ pẹ̀lú pé yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run+ tòótọ́, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.+ 13  Ṣùgbọ́n kì yóò dára rárá fún ẹni+ burúkú, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọjọ́ rẹ̀ tí ó dà bí òjìji+ kì yóò gùn, nítorí tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.+ 14  Asán kan wà tí a ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé, pé àwọn olódodo wà tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí, bí ẹni pé nítorí iṣẹ́ àwọn ẹni+ burúkú, àti pé àwọn ẹni burúkú wà tí ó ń ṣẹlẹ̀ sí, bí ẹni pé nítorí iṣẹ́ àwọn olódodo.+ Mo wí pé asán ni èyí pẹ̀lú. 15  Èmi alára sì gbóríyìn fún ayọ̀ yíyọ̀,+ nítorí pé aráyé kò ní nǹkan kan tí ó sàn lábẹ́ oòrùn ju pé kí wọ́n máa jẹ, kí wọ́n sì máa mu, kí wọ́n sì máa yọ̀, kí ó sì máa bá wọn rìn nínú iṣẹ́ àṣekára wọn ní àwọn ọjọ́ ìgbésí ayé wọn,+ èyí tí Ọlọ́run tòótọ́ ti fi fún wọn lábẹ́ oòrùn.+ 16  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, mo fi ọkàn-àyà+ mi sí àtimọ ọgbọ́n àti sí àtirí iṣẹ́ àjókòótì tí a ń bá a lọ ní ṣíṣe ní ilẹ̀ ayé,+ nítorí pé ẹnì kan wà tí kì í fojú ba oorun, yálà ní ọ̀sán tàbí ní òru.+ 17  Mo sì rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run+ tòótọ́, bí aráyé kò ti lè rídìí iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn;+ bí ó ti wù kí aráyé máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ kárakára púpọ̀ tó láti wá a,+ síbẹ̀ wọn kò rídìí rẹ̀. Bí wọ́n sì tilẹ̀ sọ pé wọ́n gbọ́n tó láti mọ̀,+ wọn kò ní lè rídìí rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé