Oníwàásù 7:1-29

7  Orúkọ sàn ju òróró+ dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.+  Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé+ àkànṣe àsè, nítorí pé ìyẹn ni òpin gbogbo aráyé; ó sì yẹ kí alààyè fi í sí ọkàn-àyà rẹ̀.  Ìbìnújẹ́ sàn ju ẹ̀rín,+ nítorí nípa ìfàro ojú ni ọkàn-àyà fi ń di èyí tí ó wà ní ipò tí ó sàn jù.+  Ọkàn-àyà àwọn ọlọ́gbọ́n ń bẹ ní ilé ọ̀fọ̀,+ ṣùgbọ́n ọkàn-àyà àwọn arìndìn ń bẹ ní ilé ayọ̀ yíyọ̀.+  Ó sàn láti gbọ́ ìbáwí mímúná ọlọ́gbọ́n+ ju láti jẹ́ ènìyàn tí ń gbọ́ orin àwọn arìndìn.+  Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí ìró àwọn ẹ̀gún lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín arìndìn rí;+ asán sì ni èyí pẹ̀lú.  Nítorí pé ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí,+ ẹ̀bùn+ sì lè pa ọkàn-àyà run.+  Òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.+ Onísùúrù sàn ju onírera ní ẹ̀mí.+  Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya,+ nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.+ 10  Má sọ pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?”+ nítorí pé ọgbọ́n+ kọ́ ni ìwọ fi béèrè nípa èyí. 11  Ọgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ogún dára, ó sì ní àǹfààní fún àwọn tí ń rí oòrùn.+ 12  Nítorí ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò,+ gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò;+ ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.+ 13  Wo iṣẹ́+ Ọlọ́run tòótọ́, nítorí pé ta ní lè mú ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́ tọ́?+ 14  Ní ọjọ́ rere, jẹ́ kí inú rẹ máa dùn,+ àti ní ọjọ́ oníyọnu àjálù, rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe èyí pàápàá gẹ́lẹ́ bí èyíinì,+ fún ète pé kí aráyé má bàa ṣàwárí ohunkóhun rárá lẹ́yìn wọn.+ 15  Ohun gbogbo ni mo ti rí ní àwọn ọjọ́ asán mi.+ Olódodo wà tí ń ṣègbé nínú òdodo rẹ̀,+ ẹni burúkú sì wà tí ń bá a lọ pẹ́ títí nínú ìwà búburú rẹ̀.+ 16  Má di olódodo àṣelékè,+ tàbí kí o fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó gbọ́n ní àgbọ́njù.+ Èé ṣe tí ìwọ yóò fi fa ìsọdahoro wá bá ara rẹ?+ 17  Má ṣe burúkú ní àṣelékè,+ tàbí kí o di òmùgọ̀.+ Èé ṣe tí ìwọ yóò fi kú nígbà tí kì í ṣe àkókò rẹ?+ 18  Ó sàn kí o di èkínní mú, ṣùgbọ́n má yọ ọwọ́ rẹ kúrò lára èkejì pẹ̀lú;+ nítorí pé ẹni tí ó bá bẹ̀rù Ọlọ́run yóò jáde lọ pẹ̀lú gbogbo wọn.+ 19  Ọgbọ́n tìkára rẹ̀ lágbára fún ọlọ́gbọ́n ju ọkùnrin mẹ́wàá tí ó wà ní ipò agbára nínú ìlú ńlá kan.+ 20  Nítorí kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.+ 21  Pẹ̀lúpẹ̀lù, má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ,+ kí o má bàa gbọ́ tí ìránṣẹ́ rẹ ń pe ibi wá sórí rẹ.+ 22  Nítorí ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ mọ̀ dáadáa, àní ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé ìwọ, àní ìwọ, ti pe ibi wá sórí àwọn ẹlòmíràn.+ 23  Gbogbo èyí ni mo ti fi ọgbọ́n dán wò. Mo wí pé: “Dájúdájú, èmi yóò di ọlọ́gbọ́n.” Ṣùgbọ́n ó jìnnà sí mi.+ 24  Ohun tí ó wá wà jìnnà réré, ó sì jinlẹ̀ gidigidi. Ta ni ó lè rídìí rẹ̀?+ 25  Èmi fúnra mi yí padà, àní ọkàn-àyà mi ṣe bẹ́ẹ̀,+ láti mọ̀ àti láti tọsẹ̀ àti láti wá ọgbọ́n+ kiri àti ìdí fún àwọn nǹkan,+ àti láti mọ̀ nípa ìwà burúkú ìyadìndìnrìn àti ìwà òmùgọ̀ ìṣiwèrè;+ 26  mo sì rí i pé: Kíkorò ju ikú+ lọ ni mo rí i pé obìnrin náà jẹ́, ẹni tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ àwọ̀n ìṣọdẹ, tí ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ àwọ̀n ńlá, tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.+ Ènìyàn jẹ́ ẹni rere níwájú Ọlọ́run tòótọ́ bí ẹni náà bá sá kúrò lọ́dọ̀ obìnrin náà, ṣùgbọ́n ènìyàn ń dẹ́ṣẹ̀ bí ó bá mú ẹni náà lẹ́rú.+ 27  “Wò ó! Èyí ni mo ti rí,” ni akónijọ+ wí, “ní mímú ohun kan tẹ̀ lé òmíràn, láti rídìí àkópọ̀,+ 28  èyí tí ọkàn mi ti ń bá a lọ ní wíwá, ṣùgbọ́n tí èmi kò tíì rí. Mo ti rí+ ọkùnrin kan nínú ẹgbẹ̀rún, ṣùgbọ́n èmi kò tíì rí+ obìnrin kan nínú gbogbo àwọn wọ̀nyí. 29  Wò ó! Èyí nìkan ṣoṣo ni mo ti rí, pé Ọlọ́run tòótọ́ ṣe aráyé ní adúróṣánṣán,+ ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwéwèé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé