Oníwàásù 4:1-16
4 Èmi alára sì padà, kí n lè rí gbogbo ìwà ìninilára+ tí a ń hù lábẹ́ oòrùn, sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára,+ ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú;+ ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.
2 Mo sì yọ̀ fún àwọn òkú tí ó ti kú jù fún àwọn alààyè tí ó ṣì wà láàyè.+
3 Nítorí náà, ẹni tí kò tíì sí,+ tí kò tíì rí iṣẹ́ oníyọnu àjálù tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn,+ sàn ju àwọn méjèèjì.
4 Èmi alára sì ti rí gbogbo iṣẹ́ àṣekára àti gbogbo ìgbóṣáṣá nínú iṣẹ́,+ pé ó túmọ̀ sí bíbá ẹnì kìíní-kejì díje;+ asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.
5 Arìndìn ká ọwọ́ rẹ̀ pọ̀,+ ó sì ń jẹ ẹran ara òun tìkára rẹ̀.+
6 Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.+
7 Èmi alára padà kí n lè rí asán tí ń bẹ lábẹ́ oòrùn:
8 Ẹnì kan ń bẹ, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kejì;+ pẹ̀lúpẹ̀lù, kò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ará,+ ṣùgbọ́n gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ kò lópin. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn:+ “Tìtorí ta ni mo fi ń ṣiṣẹ́ kárakára tí mo sì ń mú kí ọkàn mi ṣaláìní àwọn ohun rere?”+ Asán ni èyí pẹ̀lú, iṣẹ́ àjókòótì+ oníyọnu àjálù sì ni.
9 Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan,+ nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́+ àṣekára wọn.
10 Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọ́n bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.+ Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe rí fún ẹnì kan ṣoṣo tí ó ṣubú nígbà tí kò sí ẹlòmíràn láti gbé e dìde?+
11 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹni méjì bá dùbúlẹ̀ pa pọ̀, wọn yóò sì móoru dájúdájú; ṣùgbọ́n báwo ni ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè móoru?+
12 Bí ẹnì kan bá sì lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́.+ Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì.
13 Ọmọdé+ tí ó jẹ́ aláìní ṣùgbọ́n tí ó gbọ́n sàn ju ọba+ tí ó ti darúgbó ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ arìndìn, ẹni tí kò wá mọ̀ tó, tí a ó fi máa kìlọ̀ fún un mọ́.+
14 Nítorí inú ilé ẹ̀wọ̀n ni ó ti jáde lọ di ọba,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú ipò ọba ẹni yìí, aláìnílọ́wọ́ ni a bí i.+
15 Mo ti rí gbogbo àwọn alààyè tí ń rìn káàkiri lábẹ́ oòrùn, bí ó ti máa ń rí fún ọmọ, tí ó jẹ́ ìkejì, tí ó dìde dúró ní ipò èkejì rẹ̀.+
16 Gbogbo àwọn ènìyàn náà kò lópin, gbogbo àwọn tí òun wà ṣáájú wọn;+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn ẹ̀yìn ìgbà náà kì yóò yọ̀ nínú rẹ̀,+ nítorí asán ni èyí pẹ̀lú àti lílépa ẹ̀fúùfù.+

