Oníwàásù 3:1-22
3 Ohun gbogbo ni ìgbà+ tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run:
2 ìgbà bíbímọ+ àti ìgbà kíkú;+ ìgbà gbígbìn àti ìgbà fífa ohun tí a gbìn+ tu;
3 ìgbà pípa+ àti ìgbà mímúláradá;+ ìgbà wíwólulẹ̀ àti ìgbà kíkọ́;+
4 ìgbà sísunkún+ àti ìgbà rírẹ́rìn-ín;+ ìgbà pípohùnréré ẹkún+ àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri;+
5 ìgbà kíkó òkúta sọnù+ àti ìgbà kíkó òkúta jọpọ̀;+ ìgbà gbígbánimọ́ra+ àti ìgbà yíyẹra fún gbígbánimọ́ra;+
6 ìgbà wíwá+ àti ìgbà gbígbà pé ó ti sọnù;+ ìgbà pípamọ́ àti ìgbà jíjù sọnù;
7 ìgbà gbígbọ̀nya+ àti ìgbà ríránpọ̀;+ ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́+ àti ìgbà sísọ̀rọ̀;+
8 ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra;+ ìgbà ogun+ àti ìgbà àlàáfíà.+
9 Kí ni àǹfààní tí ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ní nínú ohun tí ó ń ṣiṣẹ́ kárakára nídìí rẹ̀?+
10 Mo ti rí iṣẹ́ àjókòótì tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ aráyé láti jókòó tì.+
11 Ohun gbogbo ni ó ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀.+ Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn,+ kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.+
12 Mo ti wá mọ̀ pé kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí wọ́n máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé ẹni;+
13 pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́+ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.+
14 Mo ti wá mọ̀ pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run tòótọ́ ṣe, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Kò sí nǹkan kan láti fi kún un, kò sì sí nǹkan kan láti mú kúrò nínú rẹ̀;+ ṣùgbọ́n Ọlọ́run tòótọ́ fúnra rẹ̀ ti ṣe é,+ kí àwọn ènìyàn lè máa fòyà ní tìtorí òun.+
15 Ohun tí ó wà, ó ti wà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ohun tí yóò sì wá wà ti wà nísinsìnyí;+ Ọlọ́run+ tòótọ́ sì ń wá èyí tí a ń lépa.+
16 Síwájú sí i, mo ti rí i lábẹ́ oòrùn, tí ìwà burúkú wà ní ipò ìdájọ́ òdodo, tí ìwà burúkú sì wà ní ipò òdodo.+
17 Èmi alára ti sọ ní ọkàn-àyà+ mi pé: “Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ẹni burúkú,+ nítorí àkókò wà fún gbogbo àlámọ̀rí àti nípa gbogbo iṣẹ́ ibẹ̀.”+
18 Èmi, àní èmi, ti sọ ní ọkàn-àyà mi nípa àwọn ọmọ aráyé pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣà wọ́n, kí wọ́n lè rí i pé ẹranko+ ni àwọn tìkára wọn.
19 Nítorí pé àtúbọ̀tán+ kan ni ó wà ní ti àwọn ọmọ aráyé àti àtúbọ̀tán kan ní ti ẹranko, àtúbọ̀tán kan náà sì ni wọ́n ní. Bí èkíní ti ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú;+ ẹ̀mí+ kan ṣoṣo sì ni gbogbo wọ́n ní, ìyẹn ni ó fi jẹ́ pé ènìyàn kò ní ọlá ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni gbogbo rẹ̀.
20 Ibì kan náà ni gbogbo wọ́n ń lọ.+ Inú ekuru+ ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.+
21 Ta ní ń bẹ tí ó mọ ẹ̀mí àwọn ọmọ aráyé, bóyá ó ń gòkè lọ sókè; àti ẹ̀mí ẹranko, bóyá ó ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sísàlẹ̀ ilẹ̀?+
22 Mo sì ti rí i pé kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ènìyàn máa yọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀,+ nítorí ìyẹn ni ìpín rẹ̀; nítorí pé ta ni yóò mú un wá wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?+

