Oníwàásù 10:1-20

10  Àwọn òkú eṣinṣin ní ń mú kí òróró+ olùṣe òróró ìkunra ṣíyàn-án, kí ó máa hó kùṣọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ń ṣe sí ẹni tí ó ṣe iyebíye nítorí ọgbọ́n àti ògo.+  Ọkàn-àyà ọlọ́gbọ́n ń bẹ ní ọwọ́+ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà arìndìn ń bẹ ní ọwọ́+ òsì rẹ̀.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ọ̀nà yòówù tí òmùgọ̀ bá ń rìn,+ ọkàn-àyà rẹ̀ ń ṣaláìní, ṣe ni ó sì ń sọ fún gbogbo ènìyàn pé òmùgọ̀ ni òun.+  Bí ẹ̀mí olùṣàkóso bá ru sókè sí ọ, má fi ipò rẹ sílẹ̀,+ nítorí pé ìparọ́rọ́ ń pẹ̀tù sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.+  Nǹkan kan wà tí ó kún fún ìyọnu àjálù tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, bí ìgbà tí àṣìṣe+ kan ń jáde lọ nítorí ẹni tí ó wà ní ipò agbára:+  A ti fi ìwà òmùgọ̀ sí ọ̀pọ̀ ipò gíga,+ ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́rọ̀ ń bá a nìṣó ní gbígbé ní ipò rírẹlẹ̀ lásán-làsàn.  Mo ti rí àwọn ìránṣẹ́ lórí ẹṣin ṣùgbọ́n àwọn ọmọ aládé tí ń rìn lórí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.+  Ẹni tí ń gbẹ́ kòtò, òun alára ni yóò já sí inú rẹ̀ gan-an;+ ẹni tí ó sì ń wó ògiri òkúta, ejò yóò bù ú ṣán.+  Ẹni tí ń gbẹ́ òkúta yóò fi í ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣẹ́. Ẹni tí ó sì ń la àwọn gẹdú ní láti kíyè sára pẹ̀lú wọn.+ 10  Bí irinṣẹ́ tí a fi irin ṣe bá ti kújú, tí ẹnì kan kò sì pọ́n ọn,+ nígbà náà, ìmí tirẹ̀ ni yóò fi tiraka. Nítorí náà, lílo ọgbọ́n lọ́nà tí ń mú àṣeyọrí sí rere wá túmọ̀ sí àǹfààní.+ 11  Bí ejò bá buni ṣán nígbà tí ìtujú kò tíì yọrí,+ nígbà náà, kò sí àǹfààní kankan fún ẹni tí ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ìlò ahọ́n. 12  Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n túmọ̀ sí ojú rere,+ ṣùgbọ́n ètè arìndìn gbé e mì.+ 13  Ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,+ ìṣiwèrè tí ó kún fún ìyọnu àjálù sì ni òpin ẹnu rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. 14  Òmùgọ̀ sì ń sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀.+ Ènìyàn kò mọ ohun tí yóò wá ṣẹlẹ̀; èyí tí yóò sì wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, ta ní lè sọ fún un?+ 15  Iṣẹ́ àṣekára àwọn arìndìn ń tán wọn lókun,+ nítorí pé kò sí ọ̀kan tí ó wá mọ bí a ti lè lọ sí ìlú ńlá.+ 16  Báwo ni yóò ti rí fún ọ, ìwọ ilẹ̀, nígbà tí ọba rẹ bá jẹ́ ọmọdékùnrin,+ tí àwọn ọmọ aládé tìrẹ sì ń jẹun ṣáá àní ní òwúrọ̀? 17  Aláyọ̀ ni ọ́, ìwọ ilẹ̀, nígbà tí ọba rẹ bá jẹ́ ọmọ àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tí àwọn ọmọ aládé tìrẹ sì ń jẹun ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún agbára ńlá, kì í ṣe fún mímu lásán.+ 18  Nípa ìwà ọ̀lẹ paraku ni igi ìgbéléró fi ń tẹ̀ sínú, nípa kíká ọwọ́ sílẹ̀ dẹngbẹrẹ sì ni ilé fi ń jò.+ 19  Oúnjẹ wà fún ẹ̀rín àwọn òṣìṣẹ́, wáìnì sì ń mú kí ìgbésí ayé kún fún ayọ̀ yíyọ̀;+ ṣùgbọ́n owó ní ń mú ìdáhùn wá nínú ohun gbogbo.+ 20  Ní inú yàrá ibùsùn rẹ pàápàá, má pe ibi wá sórí ọba,+ àti ní inú àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún níbi tí ìwọ dùbúlẹ̀ sí, má pe ibi wá sórí ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀;+ nítorí ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run yóò gbé ìró náà lọ, ohun tí ó ní ìyẹ́ apá yóò sì sọ ọ̀ràn náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé