Nehemáyà 7:1-73

7  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí a ti tún ògiri náà mọ,+ kíákíá ni mo gbé àwọn ilẹ̀kùn náà nà ró.+ Lẹ́yìn náà, a yan àwọn aṣọ́bodè+ àti àwọn akọrin+ àti àwọn ọmọ Léfì+ sípò. 2  Mo sì fi Hánáánì+ arákùnrin mi àti Hananáyà ọmọ aládé Ilé Aláruru+ sí ipò àṣẹ lórí Jerúsálẹ́mù, nítorí pé ó jẹ́ irú ènìyàn kan tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,+ ó sì bẹ̀rù+ Ọlọ́run tòótọ́ ju ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn lọ. 3  Nítorí náà, mo wí fún wọn pé: “Àwọn ẹnubodè+ Jerúsálẹ́mù ni a kò gbọ́dọ̀ ṣí títí di ìgbà tí oòrùn yóò mú; nígbà tí wọ́n bá sì dúró nítòsí, kí wọ́n ti àwọn ilẹ̀kùn, kí wọ́n sì fi ọ̀pẹẹrẹ há wọn.+ Kí wọ́n sì yan àwọn ẹ̀ṣọ́ lára àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, olúkúlùkù sí ibi ìṣọ́ rẹ̀ àti olúkúlùkù ní iwájú ilé rẹ̀.”+ 4  Wàyí ó, ìlú ńlá náà gbòòrò, ó sì tóbi, àwọn ènìyàn díẹ̀ ni ó wà nínú rẹ̀,+ a kò sì kọ́ ilé kankan. 5  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi fi í sínú ọkàn-àyà+ mi pé kí ń kó àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn ènìyàn náà jọ láti kọrúkọ ara wọn sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé.+ Nígbà náà ni mo rí ìwé àkọsílẹ̀ orúkọ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé+ àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ jáde wá, mo sì rí pé a kọ ọ́ sínú rẹ̀: 6  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ tí wọ́n gòkè kúrò ní oko òǹdè àwọn ìgbèkùn+ tí Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì kó lọ sí ìgbèkùn,+ tí wọ́n sì padà lẹ́yìn náà sí Jerúsálẹ́mù àti sí Júdà, olúkúlùkù sí ìlú ńlá tirẹ̀;+ 7  àwọn tí wọ́n bá Serubábélì+ wá ni, Jéṣúà,+ Nehemáyà, Asaráyà, Raamáyà, Náhámánì, Módékáì,+ Bílíṣánì, Mísípérétì, Bígífáì, Néhúmù, Báánáhì. Iye àwọn ọkùnrin nínú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì: 8  Àwọn ọmọkùnrin Páróṣì,+ ẹgbọ̀kànlá ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n; 9  àwọn ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà,+ òjì-dín-nírínwó ó lé méjìlá; 10  àwọn ọmọkùnrin Áráhì,+ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì; 11  àwọn ọmọkùnrin Pahati-móábù,+ ti àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù,+ ẹgbẹ̀rìnlá ó lé méjìdínlógún; 12  àwọn ọmọkùnrin Élámù,+ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó dín mẹ́fà; 13  àwọn ọmọkùnrin Sátù,+ òjì-lé-lẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún; 14  àwọn ọmọkùnrin Sákáì,+ òjì-dín-lẹ́gbẹ̀rin; 15  àwọn ọmọkùnrin Bínúì,+ òjì-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ; 16  àwọn ọmọkùnrin Bébáì,+ ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n; 17  àwọn ọmọkùnrin Ásígádì,+ ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ó lé méjìlélógún; 18  àwọn ọmọkùnrin Ádóníkámù,+ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé méje; 19  àwọn ọmọkùnrin Bígífáì,+ ẹgbàá ó lé mẹ́tà-dín-láàádọ́rin; 20  àwọn ọmọkùnrin Ádínì,+ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún; 21  àwọn ọmọkùnrin Átérì,+ ti Hesekáyà, méjì-dín-lọ́gọ́rùn-ún; 22  àwọn ọmọkùnrin Háṣúmù,+ ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n; 23  àwọn ọmọkùnrin Bísáì,+ ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́rìnlélógún; 24  àwọn ọmọkùnrin Hárífù,+ méjì-lé-láàádọ́fà; 25  àwọn ọmọkùnrin Gíbéónì,+ márùn-dín-lọ́gọ́rùn-ún; 26  àwọn ọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ àti Nétófà,+ ọgọ́sàn-án ó lé mẹ́jọ; 27  àwọn ọkùnrin Ánátótì,+ méjì-dín-láàádóje; 28  àwọn ọkùnrin Bẹti-ásímáfétì,+ méjì-lé-lógójì; 29  àwọn ọkùnrin Kiriati-jéárímù,+ Kéfírà+ àti Béérótì,+ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta; 30  àwọn ọkùnrin Rámà+ àti Gébà,+ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún; 31  àwọn ọkùnrin Míkímásì,+ méjìlélọ́gọ́fà; 32  àwọn ọkùnrin Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì,+ mẹ́tàlélọ́gọ́fà; 33  àwọn ọkùnrin Nébò+ kejì, méjì-lé-láàádọ́ta; 34  àwọn ọmọkùnrin Élámù+ kejì, ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀fà ó dín mẹ́fà; 35  àwọn ọmọkùnrin Hárímù,+ okòó-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún; 36  àwọn ọmọkùnrin Jẹ́ríkò,+ òjì-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún ó lé márùn-ún; 37  àwọn ọmọkùnrin Lódì,+ Hádídì+ àti Ónò,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mọ́kànlélógún; 38  àwọn ọmọkùnrin Sénáà,+ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàajì ó lé ọgbọ̀n. 39  Àwọn àlùfáà: Àwọn ọmọkùnrin Jedáyà+ ti ilé Jéṣúà, ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n; 40  àwọn ọmọkùnrin Ímérì,+ àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì; 41  àwọn ọmọkùnrin Páṣúrì,+ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tà-dín-láàádọ́ta; 42  àwọn ọmọkùnrin Hárímù,+ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún. 43  Àwọn ọmọ Léfì: àwọn ọmọkùnrin Jéṣúà, ti Kádímíélì,+ ti àwọn ọmọkùnrin Hódéfà,+ mẹ́rìn-lé-láàádọ́rin; 44  Àwọn akọrin,+ àwọn ọmọkùnrin Ásáfù,+ méjì-dín-láàádọ́jọ. 45  Àwọn aṣọ́bodè,+ àwọn ọmọkùnrin Ṣálúmù,+ àwọn ọmọkùnrin Átérì, àwọn ọmọkùnrin Tálímónì,+ àwọn ọmọkùnrin Ákúbù,+ àwọn ọmọkùnrin Hátítà, àwọn ọmọkùnrin Ṣóbáì,+ méjì-dín-lógóje. 46  Àwọn Nétínímù:+ Àwọn ọmọkùnrin Síhà, àwọn ọmọkùnrin Hásúfà, àwọn ọmọkùnrin Tábáótì,+ 47  àwọn ọmọkùnrin Kérósì, àwọn ọmọkùnrin Síà, àwọn ọmọkùnrin Pádónì,+ 48  àwọn ọmọkùnrin Lébánà, àwọn ọmọkùnrin Hágábà,+ àwọn ọmọkùnrin Sálímáì, 49  àwọn ọmọkùnrin Hánánì,+ àwọn ọmọkùnrin Gídélì, àwọn ọmọkùnrin Gáhárì, 50  àwọn ọmọkùnrin Reáyà,+ àwọn ọmọkùnrin Résínì,+ àwọn ọmọkùnrin Nékódà, 51  àwọn ọmọkùnrin Gásámù, àwọn ọmọkùnrin Úúsà, àwọn ọmọkùnrin Páséà, 52  àwọn ọmọkùnrin Bésáì,+ àwọn ọmọkùnrin Méúnímù, àwọn ọmọkùnrin Néfúṣésímù,+ 53  àwọn ọmọkùnrin Bákíbúkì, àwọn ọmọkùnrin Hákúfà, àwọn ọmọkùnrin Háhọ́rì,+ 54  àwọn ọmọkùnrin Básílítì, àwọn ọmọkùnrin Méhídà, àwọn ọmọkùnrin Háṣà,+ 55  àwọn ọmọkùnrin Bákósì, àwọn ọmọkùnrin Sísérà, àwọn ọmọkùnrin Téémà,+ 56  àwọn ọmọkùnrin Nesáyà, àwọn ọmọkùnrin Hátífà.+ 57  Àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì:+ Àwọn ọmọkùnrin Sótáì, àwọn ọmọkùnrin Sóférétì, àwọn ọmọkùnrin Pérídà,+ 58  àwọn ọmọkùnrin Jáálà, àwọn ọmọkùnrin Dákónì, àwọn ọmọkùnrin Gídélì,+ 59  àwọn ọmọkùnrin Ṣẹfatáyà, àwọn ọmọkùnrin Hátílì, àwọn ọmọkùnrin Pokereti-hásébáímù, àwọn ọmọkùnrin Ámọ́nì.+ 60  Gbogbo Nétínímù+ àti àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ. 61  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó gòkè lọ láti Tẹli-mélà, Tẹli-háṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì,+ wọn kò sì lè sọ ilé baba wọn àti orírun wọn, yálà wọ́n jẹ́ ara Ísírẹ́lì: 62  àwọn ọmọkùnrin Deláyà, àwọn ọmọkùnrin Tobáyà, àwọn ọmọkùnrin Nékódà,+ òjì-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì. 63  Àti lára àwọn àlùfáà:+ àwọn ọmọkùnrin Habáyà, àwọn ọmọkùnrin Hákósì,+ àwọn ọmọkùnrin Básíláì,+ ẹni tí ó fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Básíláì,+ ọmọ Gílíádì ṣe aya, tí a sì wá ń fi orúkọ wọn pè é. 64  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó wá àkọsílẹ̀ orúkọ wọn, láti fi ìdí ìtàn ìlà ìdílé wọn múlẹ̀ ní gbangba, a kò sì rí i,+ a sì dènà wọn láti má ṣe wọ inú iṣẹ́ àlùfáà+ nítorí a kà wọ́n sí eléèérí. 65  Nítorí náà, ẹni tí ó jẹ́ Tíṣátà+ wí fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ+ nínú àwọn ohun mímọ́ jù lọ títí àlùfáà yóò fi dìde dúró pẹ̀lú Úrímù+ àti Túmímù.+ 66  Gbogbo ìjọ náà pátá, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan ṣoṣo, jẹ́ ẹ̀gbàá mọ́kànlélógún ó lé òjì-dín-nírínwó,+ 67  yàtọ̀ sí àwọn ẹrúkùnrin+ wọn àti àwọn ẹrúbìnrin wọn, àwọn wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà-dín-lógójì ó lé mẹ́tàdínlógójì;+ wọ́n sì ní òjìlúgba ó lé márùn-ún ọkùnrin+ akọrin àti obìnrin+ akọrin. [ 68  Ẹṣin wọn jẹ́ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin, ìbaaka wọn jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún.]+ 69  Àwọn ràkúnmí jẹ́ irínwó ó lé márùndínlógójì. Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin.+ 70  Apá kan àwọn olórí+ àwọn ìdí ilé baba+ sì wà tí wọ́n fi nǹkan fún iṣẹ́ náà.+ Ẹni tí ó jẹ́ Tíṣátà+ pàápàá fún ìṣúra náà ní ẹgbẹ̀rún wúrà owó dírákímà, àádọ́ta àwokòtò, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé ọgbọ̀n aṣọ àlùfáà.+ 71  Àwọn kan lára àwọn olórí àwọn ìdí ilé baba sì wà tí wọ́n fún ìṣúra iṣẹ́ náà ní ọ̀kẹ́ kan wúrà owó dírákímà àti ẹgbọ̀kànlá mínà fàdákà.+ 72  Ohun tí ìyókù àwọn ènìyàn náà sì fi fúnni jẹ́ ọ̀kẹ́ kan wúrà owó dirákímà àti ẹgbàá mínà fàdákà àti mẹ́tà-dín-láàádọ́rin aṣọ àlùfáà. 73  Àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì àti àwọn aṣọ́bodè àti àwọn akọrin+ àti àwọn kan lára àwọn ènìyàn náà àti àwọn Nétínímù+ àti gbogbo Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú ìlú ńlá+ wọn. Nígbà tí oṣù keje dé,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wá wà nínú àwọn ìlú ńlá wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé