Nehemáyà 5:1-19

5  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn náà àti àwọn aya wọn wá ń kígbe ẹkún ńláǹlà+ lòdì sí àwọn Júù arákùnrin+ wọn. 2  Àwọn kan sì wà tí wọ́n ń wí pé: “Àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa ni àwa ń fi fúnni gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró, kí a lè rí ọkà, kí a sì jẹ, kí a sì máa wà láàyè.”+ 3  Àwọn kan sì wà tí wọ́n ń wí pé: “Àwọn pápá wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa àti àwọn ilé wa ni àwa ń fi fúnni gẹ́gẹ́ bí ohun ìdúró,+ kí a lè rí ọkà nígbà àìtó oúnjẹ.” 4  Àwọn kan sì wà tí wọ́n ń wí pé: “A ti fi àwọn pápá wa àti àwọn ọgbà àjàrà+ wa yá owó nítorí owó òde+ ọba. 5  Wàyí o, ẹran ara wa sì rí bákan náà bí ẹran ara àwọn arákùnrin+ wa; àwọn ọmọ wa rí bákan náà bí àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n kíyè sí i, àwa ń rẹ àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa wálẹ̀ di ẹrú,+ àwọn kan wà lára àwọn ọmọbìnrin wa tí a ti rẹ̀ wálẹ̀; kò sì sí agbára kankan ní ọwọ́ wa nígbà tí àwọn pápá wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa jẹ́ ti àwọn ẹlòmíràn.” 6  Wàyí o, mo bínú gidigidi ní gbàrà tí mo gbọ́ igbe ẹkún wọn àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 7  Nítorí náà, ọkàn-àyà mi ṣàgbéyẹ̀wò nínú mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí àléébù+ lára àwọn ọ̀tọ̀kùlú àti àwọn ajẹ́lẹ̀, mo sì ń bá a lọ láti wí fún wọn pé: “Ẹ̀dá owó+ ni ẹ̀yin ń fi tipátipá gbà, olúkúlùkù lọ́wọ́ arákùnrin rẹ̀.” Síwájú sí i, mo ṣètò àpéjọ ńlá ní tìtorí wọn.+ 8  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Bí ó ti wà ní agbára wa, àwa fúnra wa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa padà,+ àwọn tí a tà fún àwọn orílẹ̀-èdè; lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ̀yin fúnra yín yóò ha máa ta àwọn arákùnrin+ yín, ó ha sì yẹ kí a tà wọ́n fún wa bí?” Látàrí èyí, wọ́n kò lè sọ̀rọ̀, wọn kò sì rí ọ̀rọ̀ sọ.+ 9  Mo sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ohun tí ẹ ń ṣe kò dára.+ Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn ní ìbẹ̀rù+ Ọlọ́run+ wa nítorí ẹ̀gàn+ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọ̀tá wa?+ 10  Pẹ̀lúpẹ̀lù èmi, àwọn arákùnrin mi àti àwọn ẹmẹ̀wà mi ń yáni ní owó àti ọkà láàárín wọn. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí a dẹ́kun wíwínni yìí tí a ń wínni tòun ti èlé.+ 11  Ẹ jọ̀wọ́, pápá+ wọn, ọgbà àjàrà wọn, oko ólífì wọn àti ilé wọn, ìdá ọgọ́rùn-ún owó àti ọkà, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ fi tipátipá gbà gẹ́gẹ́ bí èlé láti ọ̀dọ̀ wọn ni kí ẹ dá padà fún wọn lónìí.” 12  Wọ́n wí pé: “Àwa yóò ṣe ìmúpadàbọ̀sípò,+ a kò sì ní béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn padà.+ A ó ṣe gẹ́lẹ́ bí o ti sọ.”+ Nítorí náà, mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí wọ́n búra láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.+ 13  Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo gbọn oókan àyà mi dànù, mo sì wí pé: “Ní ọ̀nà yìí ni kí Ọlọ́run tóòtọ́ gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò mu ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ kúrò ní ilé rẹ̀ àti kúrò nínú dúkìá rẹ̀ tí ó ní; ní ọ̀nà yìí sì ni kí ó di àgbọ̀ndànù àti òfìfo.” Gbogbo ìjọ sì wí pé: “Àmín!”+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Jèhófà.+ Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.+ 14  Ohun mìíràn: Láti ọjọ́ tí ó ti fàṣẹ yàn mi láti di gómìnà+ wọn ní ilẹ̀ Júdà, láti ọdún ogún+ sí ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ ti Atasásítà+ Ọba, ọdún méjìlá, èmi alára àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ tí ó yẹ gómìnà.+ 15  Ní ti àwọn gómìnà àtijọ́ tí ó wà ṣáájú mi, wọ́n mú kí nǹkan wúwo lórí àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì ń gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn fún oúnjẹ àti wáìnì lójoojúmọ́. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ẹmẹ̀wà wọn pàápàá jẹ gàba lórí àwọn ènìyàn náà.+ Ní ti èmi, èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀+ ní tìtorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.+ 16  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, mo lọ́wọ́+ nínú iṣẹ́ ògiri yìí, a kò sì ní pápá;+ gbogbo ẹmẹ̀wà mi sì kóra jọpọ̀ sí ibẹ̀ fún iṣẹ́ náà. 17  Àwọn Júù àti àwọn ajẹ́lẹ̀, àádọ́jọ ọkùnrin, àti àwọn tí ń wọlé tọ̀ wá wá láti inú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká sì wà nídìí tábìlì+ mi. 18  Ní ti èyí tí ó jẹ́ pé a ń pèsè sílẹ̀ lójoojúmọ́, akọ màlúù kan, àṣàyàn àgùntàn mẹ́fà àti àwọn ẹyẹ ni a ń pèsè sílẹ̀ fún mi, àti lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ mẹ́wàá-mẹ́wàà, gbogbo onírúurú wáìnì+ ní ọ̀pọ̀ yanturu. Pa pọ̀ pẹ̀lú èyí, oúnjẹ tí ó yẹ gómìnà ni èmi kò béèrè fún, nítorí pé iṣẹ́ ìsìn lórí àwọn ènìyàn náà wúwo. 19  Ọlọ́run mi, ránti mi+ fún rere,+ gbogbo èyí tí mo ti ṣe nítorí àwọn ènìyàn yìí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé