Nehemáyà 10:1-39
10 Wàyí o, àwọn tí ó fi èdìdì+ jẹ́rìí sí i ni:
Nehemáyà,+ tí í ṣe Tíṣátà,+ ọmọkùnrin Hakaláyà,+
Àti Sedekáyà,
2 Seráyà,+ Asaráyà, Jeremáyà,
3 Páṣúrì, Amaráyà, Málíkíjà,
4 Hátúṣì, Ṣebanáyà, Málúkù,
5 Hárímù,+ Mérémótì, Ọbadáyà,
6 Dáníẹ́lì,+ Gínétónì, Bárúkù,
7 Méṣúlámù, Ábíjà, Míjámínì,
8 Maasáyà, Bílígáì àti Ṣemáyà, àwọn yìí jẹ́ àlùfáà.
9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì: Jéṣúà+ ọmọkùnrin Asanáyà, Bínúì nínú àwọn ọmọ Hénádádì,+ Kádímíélì
10 àti arákùnrin wọn Ṣebanáyà,+ Hodáyà, Kélítà, Pẹláyà, Hánánì,
11 Máíkà, Réhóbù, Haṣabáyà,
12 Sákúrì, Ṣerebáyà,+ Ṣebanáyà,
13 Hodáyà, Bánì àti Bẹnínù.
14 Àwọn olórí àwọn ènìyàn náà: Páróṣì, Pahati-móábù,+ Élámù, Sátù, Bánì,
15 Búnì, Ásígádì, Bébáì,
16 Ádóníjà, Bígífáì, Ádínì,
17 Átérì, Hesekáyà, Ásúrì,
18 Hodáyà, Háṣúmù, Bísáì,
19 Hárífù, Ánátótì, Nébáì,
20 Mágípíáṣì, Méṣúlámù, Hésírì,
21 Meṣesábélì, Sádókù, Jádúà,
22 Pẹlatáyà, Hánánì, Ánáyà,
23 Hóṣéà, Hananáyà, Háṣúbù,
24 Hálóhéṣì, Pílíhà, Ṣóbékì,
25 Réhúmù, Háṣábínà, Maaseáyà,
26 àti Áhíjà, Hánánì, Ánánì,
27 Málúkù, Hárímù, Báánáhì.
28 Ní ti ìyókù àwọn ènìyàn náà, àwọn àlùfáà,+ àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn aṣọ́bodè,+ àwọn akọrin,+ àwọn Nétínímù+ àti gbogbo ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àwọn ilẹ̀ náà+ fún òfin+ Ọlọ́run tòótọ́, àwọn aya wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn, gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀ àti òye,+
29 wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin+ wọn, àwọn ọlọ́lá ọba+ nínú wọn, wọ́n sì wá sínú ipò dídáhùn fún ègún+ àti ìbúra,+ láti rìn nínú òfin Ọlọ́run tòótọ́, èyí tí a fi fúnni láti ọwọ́ Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ àti láti pa mọ́+ àti láti tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ Jèhófà Olúwa+ wa àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn ìlànà+ rẹ̀;
30 àti pé a kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, a kò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.+
31 Ní ti àwọn ènìyàn ilẹ̀+ náà tí ń mú nǹkan títà àti gbogbo onírúurú hóró ọkà wá ní ọjọ́ sábáàtì láti tà, a kò gbọ́dọ̀ gba nǹkan kan lọ́wọ́ wọn ní sábáàtì+ tàbí ní ọjọ́ mímọ́,+ kí a sì mójú kúrò nínú ọdún keje+ àti gbèsè tí ó wà ní ọwọ́+ olúkúlùkù.
32 Pẹ̀lúpẹ̀lù, a gbé àṣẹ ka ara wa lórí pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, yóò mú ìdá mẹ́ta ṣékélì wá lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run wa,+
33 fún búrẹ́dì onípele+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà ìgbà gbogbo+ àti ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo ti àwọn sábáàtì,+ àwọn òṣùpá tuntun,+ fún àwọn àsè+ tí a yàn kalẹ̀ àti fún àwọn ohun mímọ́+ àti fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.+
34 Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ṣẹ́ kèké+ lórí ìpèsè igi+ tí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn ènìyàn náà ní láti mú wá sí ilé Ọlọ́run wa,+ ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba ńlá wa, ní àkókò tí a yàn kalẹ̀, ní ọdọọdún, láti máa fi dáná lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú òfin;+
35 àti láti mú àkọ́pọ́n èso ilẹ̀+ wa àti àkọ́pọ́n èso gbogbo onírúurú èso igi+ wá ní ọdọọdún, sí ilé Jèhófà;
36 àti àkọ́bí+ àwọn ọmọkùnrin wa àti ti ẹran agbéléjẹ̀+ wa, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú òfin,+ àti àkọ́bí àwọn ọ̀wọ́ ẹran wa àti ti àwọn agbo ẹran+ wa, láti mú wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa, sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run wa.+
37 Pẹ̀lúpẹ̀lù, àkọ́so ẹ̀wẹ́ ọkà+ wa àti ọrẹ+ wa àti èso onírúurú igi,+ wáìnì tuntun+ àti òróró+ ni kí a mú wá fún àwọn àlùfáà ní àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun+ ilé Ọlọ́run wa, àti ìdá mẹ́wàá láti ilẹ̀ wa fún àwọn ọmọ Léfì,+ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn, ìyẹn àwọn ọmọ Léfì, ni wọ́n ń gba ìdá mẹ́wàá ní gbogbo ìlú ńlá wa tí ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀.
38 Kí àlùfáà, ọmọkùnrin Áárónì, sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí àwọn ọmọ Léfì bá ń gba ìdá mẹ́wàá; kí àwọn ọmọ Léfì fúnra wọn fi ìdá mẹ́wàá rúbọ lára ìdá mẹ́wàá ilé Ọlọ́run wa+ ní àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun+ ilé ìpèsè.
39 Nítorí àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì mú ọrẹ+ ọkà, wáìnì tuntun+ àti òróró wá, ibẹ̀ sì ni àwọn nǹkan èlò ibùjọsìn àti àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́,+ àti àwọn aṣọ́bodè+ àti àwọn akọrin+ wà; a kò sì gbọ́dọ̀ ṣàìnáání ilé Ọlọ́run wa.+

